Professional Documents
Culture Documents
Eyonu Fun Enikeni
Eyonu Fun Enikeni
Eyonu Fun Enikeni
Ileke itun,
Ileke ifa,
Irun abe obinrin,
Ewe eeyo
Ewe ata ijosi
Iiye agbe,
Iye aluko,
Iko Odide,
Egungun agbari ologbo die,
Awo ijimere
A o jo won papo, a o sun awo ewure ninu ina, a o ha edu ara re sinu ise ti ajo yen, a o
wa lo gbogbo re papo, a o da sinu konjo kekere kan, a o fi ori, epo ati lofinda bintu tabi
Miss paris sinu re pelu, a o fi iyerosun te ifa OgbeWonrin.
OFORE:
Siju womi, abifa gbuuru, siju womi la npe ifa, abifa gburu la npe esu odara, itun loni ki e
fi enu rere tun mi se, ifa loni ki won fenu rere fami mora, ogbo loni ki won mu temi
gbo,oro mi ka sai yo won ninu gerere, bi epo bafoju kan oorun ayo gerere, bi adi ba
foju kan oorun ayo gerere , bi ori ba foju kan oorun ayo gerere bi awo ba fi oju kanna
woranworan agun, bi oloko ba joko bi olobo ba debe a fi aye gba, Orisa sanu agbe o se
aso re laro, orisa sanu aluko ose aso re losun, Ao se iwure fun ohun ti a fe.
o.
OFO RE; Ope Eluju lo ko igba, lo ko Aake; difa fun Alaketu ti Otalele'gbesan eniyan nji
ko otalele'gbesan edi ti, Ifa ni egun kegun ko tie lee mu mi, egun iyan kii modo, egun
isu kii mobe, egun ina kii mu aaro, Ifa ni ariwo mi ti omo araye n pa ko ni le se buruku
fun mi, ariwo ega susu kii pa Odan, Ifa ni ariwo roro ko ni se Oja ni nkan, Ifa ni temi ni
tio ma se, ti ng o ma ni ire gbogbo, takese ni se lawujo owu, tijimere ni se lawujo
gbogbo eranko.
OFO-AFORAN
Adan o l'ori ade, Igbin o l'orun ejigba-ileke.
O da ko Adebori ti ise yeye adan, t'o b'aro lomo sori igi.
Oun ni Afomo!, Afomo o l'egbn, ori igi ni i gbe.
Beeni igi tio ba si fi ti afomo se, afomo naa nii pa!.
Orunmila ni nje oro yi di kaka-ngbasa, mo ni o di onigikigi.
Ifa ni "Igikigi kii maa ba Asunrin fori gbori.
Eyin adie ki i dariso okuta, igbin kii dariso iyo.
Ina ki i dariso omi.
Owo koko l'a fii wo igi.
Owo orisa la fi i wo imole.
Kujore Oluwatomisin ma di eni owo, E j'olowo o lo o.
Owo.
Afin ni Oluwatomisin, ki i se eni aa gba loju.
Aro ni Oluwatomisin, ki i s'eni aa na.
Abuke Orisa ni mi nki i seni aa di ni kanin-kanin.
E j'olowo o lo o