Professional Documents
Culture Documents
Chieftain Cy
Chieftain Cy
Installation
&
Investiture of Church Chief
On Saturday
Ifinijoye
Ti a se nni Ojo
1. Orin Akowole
(i) Okan mi, yin Oba orun
3. Bi baba ni O ntoju wa
O si mo ailera wa
Jeje l'o ngbe wa l' apa Re
O gba wa lowo ota
Yin Oluwa, yin Oluwa
Anu re yi aiye ka
5. Angel, e jumo ba wa bo
Enyin nri lojukoju
Orun, osupa, e wole
Ati gbogbo agbaiye
E ba wa yin, E ba wa yin
Olorun Olotito. Amin
2. Ibere Isin
3. Psalm 103:1-10
1. Fi ibukun fun Oluwa iwo okan mi, ati gbogbo ohun ti o wa ninu mi fi ibukun fun Oruko Re Mimo.
2. Fi ibukun fun Oluwa, iwo okan mi, ma si se gbagbe gbogbo ore re:
3. Eniti ndari gbogbo ese re ji eniti ntan gbogbo arun re;
4. Eniti nra emi re kuro ninu iparun; eniti nfi iseun-ife ati iyonu de o li ade;
5. Eniti nfi ohun didara te o lorun; beni igba ewe re di otun bi ti idi
6. Oluwa nse ododo ati idajo fun gbogbo awon ti a nilara.
7. O fi ona re han fun Mose, ise re fun awon omo Israeli.
8. Oluwa li alanu ati olore, o lora lati binu, o si po li anu.
9. Oun ki ibaniwi nigbagbogbo; beni ki ipa ibinu re mo lailai.
10. Oun ko se si wa gege bi ese wa; beni ko san fun wa gege bi aisedede wa.
2. Wa bi 'mole; si fihan wa
B' aini wa tip o to
Wa to wa si ona iye
Ti olododo nrin
4. Wa bi iri si wa bukun
Akoko mimo yi
Ki okan alaileso wa
Le yo l' agbara Re
Oluwa wa orun, iwo ti o ko wa ninu oro re pe, igbega ko ti ti ibomiran wa bikose lati
odo Re. Iwo nikansoso ni o le gbeni soke ti o si le reni sile, a ntoro Oore-Ofe re loni
sori awon omo odo Re wonyi, ti a pe sii ipo oye laarin Ijo ninu ile Re yi, fi funni ki won
le maa toju ogo re saaju ohun gbogbo, se ile won ni apeere rere ti a ko le se alaini, si
fi iwa agba wo won ati ju gbogbo re l o, ma sai fun won ni Emi Mimo re ti yio ma to
won, ki o si ma ko won.
B. IFINIJOYE
BISOBU: Mo fi iwo __________ je oye ___________ ti Ijo Marku Mimo Odumosu
Memorial, Odorasanyin ninu ile Oloorun yi niwaju Olorun Olodumare ati loju Ijo enia
Olorun, li oruko ti Baba ati niti Omo, ati niti Emi Mimo. Amin.
OLOYE: Iwo dad ororo si mi li ori, ago mi si kun akunwosile, ire ati aanu ni yio maa
to mi lehin, li ojo aiye mi gbogbo, emi o si ma gbe inu ile Oluwa lailai. Amin.
ALUFA IJO: Alufa yio mu Oloye lo si aye awon Oloye Ijo, yoo si wipe: Arakunrin
awa fi o si ori aga yi, ibujoko awon oloye ijo ki Oluwa ki o pelu re, ki Baba, Omo ati
Emi Mimo ki o si pa o mo, ni iwole ati ijade re lati oni lo ati titi lailai. Amin.
12. Orin I.O.M. 349: (Gbigba Ore- Ope Isin / Development Offering)
16. IFILO
2. Bi a wa ninu iponju
Ki y'o si nkan
Igbala kikun ni tiwa,
Ki y' o si nkan
Igbekele Olorun dun
Gbigbe inu Kristi l' ere
Emi sin so wa di mimo
Ko le si nkan