Download as docx, pdf, or txt
Download as docx, pdf, or txt
You are on page 1of 2

Oore Yeye oo, Kabiyesi omi arin ma sun

Ire omo la wu, ire alafia la n so


Eyin olubi e deyin
Eyin eleye e peyinda
Ere omo la n se
Oso Ile e peyinda
Oke omo la n re
Elebologun e deyin
Ile olomo yoyo la n lo
Eyin eleye e peyinda
Abinu Eni e Bila sehin

Abideremon
Oyeeyee nimon
Omi arin ma sun
Gba ire oni oo
Ta ala sori mi
Ki o Ta ala sori ebi ati ara

Osun a ti bo e loni oo
Ki o Je ki ire gbogbo Je tiwa
Nitro ifa ni
Siyin keke, Siyin keke
Ti Afinju ba ji
A si eyin keke si oko
Awon obun ni won ji ni kutukutu yonfa
Ise apon o lori
Ti abiyamon lo San die
Awon lodifa fun Onijumu inaki
Omo Aroodo ide gun iyan Je
Nijo ti o n sunkun alaini ire gbogbo
Won ni a ni ire lopo lopo
Osun ni ki o ma bo
Oni ase ti o ba bini
Yeye wa otoro Efon
Osun Ewuji ni won n bo nibe
Ti won ba ni
Onijumu inaki se be o bo osun
O di onire gbogbo
Emi Babalawo Fatalabi ke pe iwo Osun loni Je ki emi
naa di onire gbogbo.
Ase

You might also like