Professional Documents
Culture Documents
Agbeywo Awon Iwe Itan
Agbeywo Awon Iwe Itan
Ọ̀RUN TÍ ÈKEJÌ SÌ Ń JÉ ̣ IDÀ AHUN ÀTI ÌWÉ ERÉ ONÍṢE KAN TÍ ÒUN Ń JÉ ̣ GÙDÙGÚDÚ
ỌMỌ ỌBA ADÉBÍSÍ ADÉSÍGBÌN LÓ KỌ ÀWỌN ÌWÉ NÁÀ; ILÉ-IṢÉ ATÈ W
̣ ÉTÀ AYUS
Ẹ kú iṣé ̣ ọpọlọ
Ọmọ Ọba Adébísí Adésíngbìn
Pátákó ẹkùn, kaka tíí taja lé ̣nu
Onígègé wúrà, ẹrẹbẹ ọkùnrin
Ìgbín tẹnu mógi ó gùn ún
Àjànàkú èèyàn abìrù bàǹbà
Mo kí wọn wí pé wó ̣n kú àṣeyọrí àti àmókègùn. Wó ̣ kú ọgbó ̣n inú àti àfòyegbékalè.̣ Yàtò ̣ sí ìnáwó-nára
òǹkò ̣wé lórí bùkátà ìwé kíkọ, afara-ẹnyìn a tún máa mú ni lómi ara. A sì máa lé ò ̣pò ̣lọpò ̣ ènìyàn sá
sé ̣yìn. Ìdí nìyí tí ó fi jé ̣ wí pé kìí ṣe gbogbo ẹranko níí ṣu bó ̣tọ - gbogbo alákò ̣wé kó ̣ ló lè ní àrògún àti
1
àròjinlè ̣ nípa ìwé àkàgbádùn kíkọ. Ṣùgbó ̣n mo bá yín dúpé ló ̣jó òní pé ẹ kóta, ẹ kìje lórí àwọn ìwé náà
lójú è ̣mí yín. Ọmọ orí-odó ti tó ènìyàn lù pa láàyè ò ̣tò ̣ kí á tó ṣè ̣ṣè ̣ wá tún so oògùn mó ̣ ọn. Láti kọ ẹyọ
ìwé kan tó gbóuńjẹ fé ̣gbé ̣ jáde ní irú àṣìkò tí a wà yìí, a máa fi ni lògbò-lògbò, kí a má ṣè ̣ṣè ̣ wá sọ oríṣìí
ìwé mé ̣ta papò ̣ lé ̣è ̣kan ṣoṣo. Tẹnu kó ̣, aláyà ńlá náà ló le gbé odó ńlá. Àfè ̣yin náà.
Mo mọ nǹkan tí mo ń sọ nígbà tí mo sọ pé àfi irú mègídá alákò ̣wé bí ọmọ-ọba Bísí Adésígbìn ló
tó irú ò ̣ṣó ̣ bé ̣è ̣ fi ṣe ẹwà. Olùkọ akó ̣ṣé ̣-mọṣé ̣ ni òǹkò ̣wé yìí bè ̣rè ̣ láti ilé ìwé olùkọ́ onípòkẹta, onípòkejì
àti onípò-kínní. Pabanbarì rè ̣ ni wí pé wó ̣n tún kó ̣ è ̣kó ̣ iṣé ̣ olùkó ̣ ní àkó ̣yege àti èkó ̣-gbàmì-ìràwò ̣ ní ilé
ìwé gíga Yunifásitì Ifè ̣. Owó ̣ tiwọn ló gbè ̣yìn nínú àwọn tí wó ̣n gba ìwé è ̣rí Yunifásitì Ifè ̣, gbogbo àwa
yòókù, Ọbáfé ̣mi Awóló ̣wò ̣ Yunifásitì ni a lọ. Òǹkọ̀wé yìí siṣé ̣ alábòójútó ètò ìdìbò láìfẹṣè ̣-kọ, kódà, ó
tún bá wọn ṣakò ̣wé ètò è ̣kó ̣ ní ilé-iṣé ̣ ìjọba-ìbílè ̣ Gúúsù Ifè.̣ Gbogbo àwọn ìrírí wò ̣nyí mú kí àmù ọgbó ̣n
àti ti ìrírí rè ̣ kún fó ̣fó ̣. Nínú irú àmù yìí àti ìwo-ṣàkun àyíká ilè ̣ Yorùbá tí wó ̣n bí òǹkò ̣wé yìí sí ló mú kí
Ó ti tó bí ọgbò ̣n ọdún báyìí tí èmi àti òǹkò ̣wé yìí ti ń jiyán kangbá ní Yunifásitì Ifè.̣ Ipò alàgbà,
aṣíwájú àti akíkanjú ni wó ̣n sì wà fún irú wa láti ìgbà náà. Lóòótó ̣, ọpé ̣ ńlá-ńlá ni a rí dá lórí ìgbésí ayé
wọn nítorí pé Ọló ̣run-ọba kò fi wó ̣n pamó ̣ láti bí ọgbò ̣n ọdún náà títí di àkókò yìí ṣùgbó ̣n èrò àwa è ̣dá
ènìyàn ni bíi kí irú wọn ti di òjìnmì kòfésò ̣ ní Yunifásitì ńlá kan ní irú sáà tí a wà yìí nítorí pé àwọn ẹni
tí kò rí bí abahun ń wè ̣wù abọna, abò ̣ǹtóórí ajíbó ̣nà baba ahun. Ṣùgbó ̣n gé ̣gé ̣ bí mo ti sọ ṣáájú, kò sí
kòfésò
̣ ̣ kankan tó le rí àga wọn gbé jùnù sé ̣yìn agbo nídìí ìmò ̣ è ̣kó ̣ ìjìnlè ̣ àṣà àti lítírésò ̣ Yorùbá yìí. Èṛ í
máa jé ̣-mi-nì-só ni àwọn ìwé tí wó ̣n ti kọ sáájú lòníì yìí àti àwọn ìwé mé ̣ta ò ̣tò ̣ò ̣tò ̣ tí a ń kó jáde lónìí yìí.
Iṣé ̣ àtinúdá, iṣé ̣ ọnà, àfòye ṣàlàyé gbáà ní ò ̣kò ̣ò ̣kan wọn jé ̣ gé ̣gé ̣ bí a óò ti ṣe máa ṣí i kalè ̣ láwé ̣-láwé ̣
nínú àgbéyè ̣wò tí n óò gbìyànjú láti ṣe láìpé ̣ yìí. Ṣùgbó ̣n mo gbó ̣dò ̣ tètè jé ̣wó ̣ wí pé àwọn tí wó ̣n ṣe
àgbékalè ̣ ètò ayẹyẹ òní ti kìlò ̣ fún mi wí pé àwọn kò fé ̣ kí n fàṣìkò ṣòfò lórí àròyé nítorí pé àwọn fé ̣ kí
ẹni kò ̣ò ̣kan tó wá sí ibi ayẹyẹ òní gbìyànjú láti ra àwọn ìwé náà nítorí wí pé a kìí gbókèèrè mọ adùn ọbè ̣
àti pé a kìí fi ẹnu ẹni ẹlé ̣ni tó ̣ ọtí wò. Yàtò ̣ sí èyí. Gbogbo wa la mọ̀ pé ọbè ̣ tó bá dùn bí irú èyí, owó ló
ẹni tó wẹ òkun. Ọ̀nà tí n óò sì gbé e gbà ni pé n óò máa mú kókó ò ̣rò ̣ mi láti inú ìwé tí àlàyé mi bá ti
2
jẹyọ kìí ṣe pé n óò kúkú máa mu ìwé náà ló ̣kò ̣ò ̣kan. Ẹniké ̣ni tí ó bá ń fé ̣ àgbé ̣yìn àti àgbé ̣-gbòòrò yóò
nílò kí òun fúnra rè ̣ lọ ra àwọn ìwé náà ni. Ẹni tí yóò lo orí ahun tí yóò lo è ̣dò ̣ ahun, odidi ahun ni yóò
rà.
Àwọn kókó tí iṣé ̣ mi yóò jẹ mọ́ lórí ìdúró mi yìí nípa àwọn ìwé mé ̣tèẹ̀ ̣ta tí mo ń sò ̣rò ̣ rè ̣ yìí lọ
báyìí:
(vi) Ẹ̀kó ̣ tàbí iṣé ̣ tí òǹkò ̣wé wò ̣nyí fé ̣ jé ̣ tàbí tí ó fé ̣ rán sí àwùjọ
(viii) Àgbálọgbábò ̣
Lé ̣yìn àwọn àlàkalè ̣ tí mo ṣè ̣ṣè ̣ ṣe tán yìí, ǹ bá pé kí n lọ jókòó nítorí pé mo ti yàwòrán ohun tí mo fé ̣ sọ
tán ṣùgbó ̣n kí ò ̣rò ̣ má baà dà bí ẹni tí ó lá àlá tí kò leè rọ, ẹ jé ̣ kí n fún yín ni àwọn ìtó ̣wò ráńpé ̣ nípa
Mo ti sọ sáájú wí pé ipò alàgbà ni òǹkò ̣wé yìí wà fún irú wa. Ọmọdé kò sì le mọ ìtàn - mọ ìtàn
kí ó le sọ irú asọ tí a wò ̣ ló ̣jó ̣ tí a ń fé ̣ ìyá rè ̣. Àfi bí yóò bá sẹ àgbó ̣wí àti àwígbó ̣. È ̣gbìn kò si le jọ è ̣ló ̣.
Yàtò ̣ sí ohun mo ti sọ díè ̣ nípa ìrírí ayé òǹkò ̣wé yìí nínú ìfáàrà tí mo ṣe sáájú àwọn nǹkan díè ̣ tí n kò tíì
mé ̣nu bà ni wí pé ọmọ ọba ni òǹkò ̣wé yìí ní ìlú Ìfé ̣tè ̣dó ṣùgbó ̣n tí ó ní ìrírí ìgbé-ayé oko, ìgbé-ayé tísà
pàápàá jù lọ nígbà tí è ̣kó ń ṣè ̣ṣè ̣ fẹṣè ̣ rinlè ̣ láti ò ̣dò ̣ àwọn ẹlésìn
̣ kírísítì ní ilè ̣ Yorùbá. Ní ayé ìgbà náà, kò
sí ìjà è ̣sìn. Inú àwo kan náà ni gbogbo ìran Yorùbá ti ń rùn ọbè ̣ àjọse àti àjọwà. Inú àmù ìrírí yìí ni
òǹkò ̣wé ti bù mu láti ṣe ìgbédìde àtinúdá ìtàn lítírésò ̣ rè ̣ èyí tó kó jọ sínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ rè ̣.
Ọ̀pò ̣lọpò ̣ àwọn òǹkò ̣wé ni àkíyèsí fi hàn wí pé ìrírí ayé àti èdè tiwọn gan-an kò tó nǹkan dé bi ohun tí
3
wọn le fi han elòmìíràn. Ebi ló ń pa wó ̣n. Níbí yìí ni ọmọ ọba Bísí Adésígbìn ti ta ò ̣pò ̣lọpò ̣ akẹgbé ̣ rè ̣
yọ. Làbẹlàbẹ kò dapò ̣ mọ́ koríko odò yòókù – gbọgbọ lọwó ̣ yọ ju orí ẹni lọ.
(a) Létà
̣ sí Àwọn Ará Ọ̀run
Ẹ̀dá ìtàn kan tí orúkọ rè ̣ ń jé ̣ Àkàngbé ní Èlú Ìwéré tí ń gbé Àdúgbò Ayésan Ajárógungbó ní ìlú
Ifè ̣té ̣dò ló kọ lé ̣tà sí àwọn òbí rè ̣ tí wó ̣n ti kú láti fi gbogbo ìṣè ̣lè ̣ tó ń lọ ló ̣wó ̣-ló ̣wó ̣ nílé ayé lónìí tó wọn
létí. Èyí túmò ̣ sí pé LÉ ̣TÀ ni gbogbo ohun tó ń bẹ nínú ìwé náà jé ̣ a já a kà ni. Àbí kí a sọ pé àwa kí
wọn kó ̣ lé ̣tà náà sí. Kò rí béẹ̀ ̣ o nítorí kí adití ó lè baà gbó ̣rò ̣ ni a ṣeé sọ ó ̣ lójú ọmọ rè ̣ ogun tó ń bò ̣ ni ajá
fi ń gbó láti àdúgbò ajá rógungbó níbi tí lé ̣tà náà ti wá. Ayé kìí de orí ẹni kó bàjé ̣, àfi àìmò ̣wá-hù-ẹni.
Ọ̀ró ̣ pò ̣ nínú ìwé kó ̣bò ̣: Nínú àwọn nǹkan tí Àkàngbé fé ̣ kí àwọn òbí rè ̣ ó mò ̣ ni ètò ìdílé, ètò ìjọba, àṣà,
ọrò ̣-ajé, ètò è ̣kó ̣, èdè, ìrìnnà, oúnjẹ, ìrònú-ènìyàn, ìmúra, è ̣sìn, abbl, tí ó ti yàtò ̣ lóde òní. Nǹkan ti yí
padà sí bí àwọn òbí wò ̣nyí ti fi sí. Àìsunwò ̣n ara ayé ló mú Àkàngbé rántí àwọn ara ò ̣run tó fi kọ lé ̣tà
Ní ti ìwé ìtàn àròsọ idà ahùn è ̣wè ̣, ìwé náà jé ̣ olójú ìwé mé ̣rìn-lé-lógóje níbi tí òǹkò ̣wé ti siṣé ̣
aríran, oníwàásù, atáyéṣe àti alágogo-ìkìlò ̣ fún gbogbo è ̣dá ènìyàn pé kí wọn sọ́ ìwà hù, kí ajá só ̣ omi lá
kí wó ̣n ma bà a lá aró, kí ìjìmèrè sọ igi gùn kí wọn má baà gun igi aládi nítorí gbogbo ìwà ibi tí è ̣dá bá
hù láyé fúnra rè ̣ ni yóò ké ̣san rè ̣. Àti pé bí abé ̣ré ̣ bí abé ̣ré ̣ ni à á sèké, ló ̣jó ̣ tó bá tó ọkó ̣ rọ ni sa ni lójú
gan. “Ẹni tó bá ń re àjò àyúnbò ̣, tó ṣu só ̣nà ní àlọ, bó bá ń padàbò ̣, ògò ̣ò ̣rò ̣ esinsin ni yóò kí i kú àbò ̣.
Ìlú Òjétèdó ni ibùdó ìtàn náà. Àwọn ìrírí ilé-ọlá ní àfin ọba, àti ìdààmú ilé olórogún ní orí oyè
níbi tí ó ti jé ̣ wí pé ìpín, ò ̣ràn ló so mó ̣ ìpín ọlá, ìpín àìlesùn ló dira mó ̣ dàńsáákì. Bé ̣è ̣, ò ̣rànlọlá, dandan
sì ni ọlà ọmọ ènìyàn. Àwọn àsamò ̣ wò ̣nyí ni kókó inú ìwé Idà Ahùn. Òǹkò ̣wé sì gbé ìtàn inú ìwé náà ká
orí è ̣dá ìtàn kan tí a mò ̣ sí Arékemáṣe. Mé ̣jọ ò ̣tò ̣ò ̣tò ̣ ni àwọn olorì tí Arékèmáṣe ọló ̣jè ̣ ti ìlú Ọ̀jé ̣tè ̣dó ni.
Ó sì tún ní àwọn ayaba mé ̣fà mìíràn nínú ààfin rè.̣ Ní ìbè ̣rè ̣ pè ̣pè ̣ Jókòótọlá ni ààyò ọba Arékèé yìí
4
ṣùgbó ̣n ìwà ìjọra-ẹni lójú, àìmò ̣-ọkọ-pó ̣nlé mú kí ó ṣìwàhùn ló ̣jó ̣ tí kábíyèsí ń ṣe ayẹyẹ. Àtipé, bí ti ìkà
Báwo ni tí Oyíndàmó ̣lá ọmọ òrukàn lásán-làsàn tí ó padà di ayaba, ẹni tí wó ̣n mú wá láti ìlú
Ògún-Olówu tí ọba fi ró ̣pò Jókòótadé yóò ṣe dára - orí tí yóò súpó, kìí jé ̣ kí aláìsàn ó yè. Òrìṣàdàpò ̣ ni àtè ̣lé
rè ̣ ó sì rò wí pé òun ni ipò olórí kan ṣùgbó ̣n ifá kò mú un. Inú rè ̣ sì bàjé ̣ gidigidi. Ó dìtè ̣ láti fún ọba ní májèlé jẹ
òun pè ̣lú Jókòótadé olorì àgbà, olorì Aláse àti Òrìṣàdáyó ̣. Awo ya, ọba sì fábínú yọ. Wó ̣n dá ẹjó ̣ ikú fún gbogbo
Ìwé yìí yàtò ̣ nítorí pé ohun nìkan ni eré onítàn, tí a ń pè ní dírámà. Ǹjé ̣ kín ní ń jé ̣ ìgùdùgúdú. Iṣú
tó ni májèlé nínú kan báyìí ni. Ènìyàn kìí jẹ é ̣ ṣùgbó ̣n ó fojú jọ èsúrú tí à ń jẹ púpò ̣. Ìdí nìyí tí Yorùbá fi
Bí a bá rí ènìyàn tó jé ̣ ajogun abé ̣ ò ̣dè ̣dè,̣ tó ya oró apani ṣùgbó ̣n tí kò gbé ìwà ìkà náà lé ojú -
Ìgùdùgúdú ènìyàn gbá a ni olúwaa rè ̣. Àwọn àgùntàn lójú ṣùgbó ̣n ìkookò níkìn. Inú irú àkíyèsí yìí ni
Ìran mó ̣kànlá ni àwọn ìran tó wà nínú ìwé eré onítàn náà. Òǹkò ̣wé sì gbé àwọn ìran náà ka orí
àwọn ìṣè ̣lè ̣ onírúurú bí ìwà ò ̣kánjúwà, ò ̣kúndùn, oú, ẹjó ̣-elé ̣jó ̣, oògùn ìkà, ò ̣dàlè ̣, àìnítẹló ̣rùn, tó máa ń rí
ọkọ ìyàwó, àwọn orogún àti àwọn ọmọ wọn lógun nínú ilé olórogún.
Àyángbèmí ni ọkọ, Moní ni ìyàwó àgbà, Kè ̣kè ̣ ló wà láàrin. Bó ̣sè ̣dé sì ni ìyàwó ìkẹyìn wọn
léńjeléńje. Nínú eré náà, Kè ̣kè ̣ ni igi wó ̣ró ̣kó tí daná rú, àti ààrò wò ̣rò ̣kò ̣ tí da ọbè ̣ sáàrò. Àjé ̣ paraku ni
ìyá Kè ̣kè ̣ fúnrarè.̣ Ṣe ìyàwó burúkú kò ṣòro fé ̣, àna burúkú ló ṣòro jù. Nítorí náà, Kè ̣kè ̣ ya olóògùn ìkà
tó gbówó ̣.
Bí Àyángbèmí sì ti ń gbìyànjú láti rí i wí pé òun ṣe déédéé láàrin àwọn ìyàwó òun tó, ìwà owú
jíjẹ Kè ̣kè ̣ kò jé ̣ kí omi ò ̣dè ̣dè ̣ Àyángbèmí kí ó tòòrò. Ojú ọkọ ìyàwó yìí rí màbo. Ẹ sì máa wò ó,
pé ̣pé ̣fúrú Kè ̣kè ̣ ló pò ̣ jù láìtètè mò ̣ pé òun gan-an ni ajogun abé ̣ ò ̣dè ̣dè ̣, àní òun ni Ìgùdùgúdú sojú dèẹ̀ ̣rè ̣
pọmọ jẹ. Ṣùgbó ̣n ṣá lé ̣yìn-ò ̣-rẹyìn, òtító ̣ lékè. Ajá relé ẹkùn, ajá sì bò ̣. Àwọn ara ilé Àyángbèmí panu pò ̣
5
pé kí Kè ̣kè ̣ ó digbá-dagbò ̣n rè ̣ kò fi ilé Àyángbèmí sílè ̣ nítorí bí iró ̣ bá lọ lógún ọdún, ọjó ̣ kan ṣoṣo
lòóótó ̣ yóò bá a.
A ti sọ saájú pé ìwé ìtàn Àròsọ tí a mò ̣ sí NOVEL ni Lé ̣tà sí Àwọn Ará Ọ̀run àti Idà Ahun
ṣùgbó ̣n eré onítà – Drama – ni Ìgùdùgúdú ní tirè ̣. Àwọn ìtàn tó jẹ mó ̣ ojú-ayé ni gbogbo wọn. Àwọn
è ̣dá ìtàn inú wọn náà kìí síì ṣe mérìíírí bí àǹjò ̣ò ̣nú. Nítorí náà Lé ̣tà ni ẹni tí ó kọ ó ibi tó ń gbé àti àwọn
iburu tí a mò ̣ mọ́ Lé ̣tà gbè ̣fé ̣ irú èyí tí Lé ̣ta náà jé ̣ mó ̣. Tí a bá yọwó ̣ ìbánisò ̣rò ̣ ojukórojú, ò ̣nà ìbánisò ̣rò ̣
tí ó tún dé àwùjọ Yorùbá lé ̣yìn ìlànà àròkọ ni Lé ̣ta. Ibi tí òǹkò ̣wé kò lè dé ni ó fi Lé ̣tà ránsé ̣ sí. Ó sì lérò
wí pé ojú àlá ni òun yóò ti gbó ̣ èsì èyí tí ó yàtò ̣ sí ìlànà tó gbé tirè ̣ gbà. Ìwé ìtàn Àròsọ Ìgùdùgúdú fara
pé ̣ àló ̣ àpagbè tí a ti máa ń gbìyànjú láti mú kókó è ̣kó kan tàbí òmííràn jáde. Orísìírísìí è ̣kó ̣ bí tí lako
ìwà owú jíjẹ, olè, àìnífè ̣é ̣, àìlé ̣mi-ìrè ̣lè ̣ àti fífi yé ni pé è ̣san kò gbóògùn ni ó pò ̣ nínú àló ̣ tí àwọn òǹkò ̣wé
lítírésò ̣ náà sì máa ń gbeyọ nínú ìwé wọn. Èyí kò yọ ọmọ ọba Adésígbìn sílè,̣ àwọn ìran kò ̣ò ̣kan tí ó wà
nínú Ìgùdùgúdú àti orí kò ̣ò ̣kan nínú Idà Ahun ló nkó ni ló ̣kàn ró. Orí mé ̣jè ̣è ̣jọ inú ìdáhùn tilè ̣ fọwó ̣ kó ̣
ara wọn bí owú àwọn ni. àwọn àkànlò-èdè tí òǹkò ̣wé fi ṣe àkòrí orí kò ̣ò ̣kan mú kí àwọn kókó inú ìwé
náà ṣe àfòmó ̣ iṣé ̣ àti àkíyèsí tí ó jẹ òǹkò ̣wé yìí lógún. Àní, a lérò pé ò ̣rò ̣ ti parí ni nínú Ìgùdùgúdú lé ̣yìn
rìgímò ̣ olorì Jókòótọlá àti Olórí Aláṣe àfi ìgbà tí ò ̣rò ̣ Oyíndàmó ̣lá àti Kábíyèsí tún yí wọ ẹhun ìtàn náà.
A sì tún fura pé àwọn ìwé mé ̣tè ̣è ̣ta kò fi ihun jọ ara wọn, olúkúlùkù ló dasọ ró olú è ̣dá-ìtàn tirè ̣, ló sì fi
Ọ̀kan nínú orísun àwọn ìwé tí a ń sàgbéyè ̣wò rè ̣ yìí ni ìrírí òǹkò ̣wé gé ̣gé ̣ bi ẹni tí ó ti ríran rí
wàhálà àwọn orí adé àti ọrùn ìlè ̣kè ̣ nínú ààfin. Yàtò ̣ sí èyí, òǹkò ̣wé yìí ṣàfihàn ìwà orogún ṣíṣe láàrin
àwọn obìnrin níbi tí wó ̣n bá ti pé méjì-mé ̣ta tàbí jù béẹ̀ ̣ lọ, èyí tí kò sàìní ti rí ní agbo ilé ńlá tí òun fúnra
rè ̣ ti dìde.
Àwọn nǹkan mìíràn tó tún dà bí àtè ̣gùn fún òǹkò ̣wé yìí ni ìrírí rè ̣ gé ̣gé ̣ bí ẹni tó ti bá àwọn ìyá
àgbàlagbà kọ lé ̣tà sí àwọn ọmọ wọn tàbí ẹbí onítò ̣hún lé ̣yìn odi. È ̣wè ̣, ọgbó ̣n ìtà àròsọ, ìgbé - ò ̣rò ̣-kalè ̣
6
lásìkò ìparí-ìjà láàrin ọkọ-lóbìnrin, ìtàn-sísọ, àló ̣, orin olóbìnrin-ilé hàn ketekete nínú ìhun àti ìgbé ̣kalè ̣
Ẹ̀wè ̣, bí ó tilè ̣ jé ̣ wí pé òǹkò ̣wé lo àwọn ọgbó ̣n àtinúdá ti ara rè ̣ ṣùgbó ̣n àwọn ìrírí rè ̣ gé ̣gé ̣ bí
ọmọlé ̣yìn kìrìsté ̣nì, tó ti ka Bíbélì inú ìwé Esiteri hàn nínú è ̣hun ìtan rè ̣. Bí àpẹẹrẹ, ìtàn bí Ẹsiteri ṣe di
ayaba nínú Bíbélì kò yàtò ̣ sí ti Oyíndàmó ̣là nínú ìwé Idà Ahun. Òtító ̣ àti ìwà akin tí a ká mó ̣ Oyín
Máyò ̣wá ló ̣wó ̣ bá ti Modekai inú Bíbélì pè ̣lú. Bé ̣è ̣ ìwà mùtúmùtè ̣ Hamani nínú Bíbélì àti àtubò ̣tán rè ̣ kò
fi gbogbo ara yàtò ̣ sí ara wọn bí a bá wo ti è ̣dá ìtàn Olórí Aláàbò nínú Ìwé Idà Ahun tí a ń wì yìí.
Látòkè délè ̣, àwọn ènìyàn àwùjọ ìgbàlódé yìí tí òǹkò ̣wé ń kọ àwọn ìwé rè ̣ fún ló ń darí rè ̣ nínú
irú àwọn è ̣dá ìtàn tí yóò lò láti kóp nínú lítírésò ̣ kò ̣ò ̣kan. Ohun tí a ń wí níhìn-ín ni pé ìtàn tó bá ojú-ayé
mú, tó tó ̣ka sí irú ìṣè ̣lè ̣ àwùjọ ni àwọn ìwé lítírésọ̀ náà.
Bí àpẹẹrẹ, olórí è ̣dá ìtàn kò ̣ò ̣kan kópa látòkèdélè, àwọn è ̣dá-ìtàn amúgbálé ̣gbè ̣é ̣ náà sì dá kún
gígún ipa tó ní àyọrísí nínú àwọn àtubò ̣tán inú ìtàn kò ̣ò ̣kan. Kò sí èyí tó jọ ìtàn mérìíírí nínú àwọn ìwé
náà.
A kìí gbé àwòrán gàgàrà, kí a máa fi orí rè ̣ ti nǹkan ni ìṣàmúlò kókó è ̣kó ̣ fún lítírésò ̣ nítorí wí pé
Orísìírísìí iṣé ̣ ni òǹkò ̣wé yìí ràn sí onípòjipò ènìyàn láàrin àwùjọ. Yorùbá - bè ̣rè ̣ látorí ọmọdé títí
dé orí àwọn àgbàlagbà nínú ìwé Lé ̣tà sí Àwọn Ará Ọ̀run. Bákàn-náà ni òǹkò ̣wé tún ran oníruurú iṣé ̣ sí
ìjọba tó ń sàgbékalè ̣ ètò è ̣kó ̣. Kò fé ̣ kí gbogbo àgbà tó jẹ è ̣ṣè ̣bì kan yajú kalè ̣ máa wòran lásán, ó fé ̣ kí
wọn ó pe ara wọn jọ ni. È ̣wè,̣ àwọn olórí nínú ilé, níbi iṣé,̣ nínú ẹgbé,̣ ló ̣kùnrin-lóbìnrin ni ìwé Idà
Ahun ni è ̣kó ̣ fun pé ò ̣dàlè ̣ bá ilè ̣ kú, ẹni tó bá dalè,̣ yóò bá ilè ̣ lọ. Ó fé ̣ kí gbogbo è ̣dá alààyè ó mò ̣ pé
àṣegbé kankan kò sí, àṣepamó ̣ nìkan ló wà. Èṛ ín kò sí lé ̣rè ̣ké ̣ ẹni tó yìnbọn jẹ, àyàfi tí ìbọn kò bá ró. Iṣé ̣
7
mìíràn tí òǹkò ̣wé yìí tún dàníyàn ni pé ó fé ̣ kí tolórí-tẹlé ̣mù ọmọ Yorùbá mọ èdè náà sọ, kí wọn mò ̣ ó ̣n
gbé kalè ̣. Nítorí pé ẹni tí a bá bí sínú ọgbà, kò gbó ̣dò ̣ si iṣu yọ.
Àkíyèsí kan tó ṣe pátákì tí mo fé ̣ kí gbogbo wa ó mú lọ sílé ni pé àwọn ìwé ọmọ ọba Bísí
Adésígbìn tí a ń kó jáde lónìí wò ̣nyí kìí ṣe ìwé lásán, ìwé akó ̣mọ-lédè gbáà ni. Òwé kún inú rè ̣ fó ̣fó ̣,
àkànlò-èdè lu inú rè ̣ pa rìbìtì-rìbìtì. Àfiwé tààrà, ẹlé ̣lò ̣ó ̣ àti ọló ̣nà kò níye. Mélòó la óò lá nínú ò ̣pò ̣ iyò ̣.
Mo kíyèsí i pé inú ìwé Idà Ahun ni òǹkò ̣wé yìí ti fakọ yọ jù bí a bá ń ṣe ìgbéléwò ̣n aáyan rè ̣ nípa
ìlò èdè. Ọmọ-ọba Adésígbín ṣè ̣dá òwe, ó ń sọ ìṣè ̣lè ̣ dòwe, ó ń tún òwe rọ, ó ń kan òwe méjì-mé ̣ta pò ̣, ó
ń ṣàlàyé òwe. Ó sì ń pààrò ̣ òwe. Ẹní bá bímọ níbejì nìkan ló le sọ èjìré,̣ àfi ẹni tó bá ka àwọn ìwé ọmọ-
ọba Bísí Adésígbìn nìkan ló le mọ ọkùnrin yìí gan-an gé ̣gé ̣ bí ọmọkùnrin jangan-jangan èkejì ẹkùn.
Nínú ìlò èwe àti àgbékalè ̣ ìtàn àròsọ, Alàgbà Oládè ̣jọ Òkédìjí nìkan ni a lè fi ọkùnrin yìí wé. Àdánù
gbáà ni yóò sì jé ̣ bí a kò bá bá òǹkò ̣wé yìí ra ìwé náà, kí ẹni tí ó rà á polówó rè ̣ fún àwọn tí kò tíì ṣe bé ̣è.̣
ÌGÚNLẸ̀