Download as pdf or txt
Download as pdf or txt
You are on page 1of 1

CHRIST FOR ALL ANOINTED MIRACLE MINISTRY (CFAM)

Beh Behind Olagunsoye Oyinlola Primary School, Iloromu Quarters, Ile-Ife, Osun State

DIDAGBASOKE NINU IWA MIMO:


IWA MIMO NINU BI A SE NSORO, BI A SE NSINMI ATI NINU IBASEPO

AKOSORI: “Nitori naa eyin olufe, bi a ti ni ileri wonyi, eje ki a we ara wa mo kuro ninu
gbogbo egbin ti ara ati ti emi, ki a maa so iwa-mimo dipipe ni iberu Olorun” - 2 Korinti 7:1.

ORO AKOSO
O se ni laanu pe opolopo Kristieni lo ti gbe oro iwa-mimo ti segbe kan, sibe, ape wa si igbe aye ati ise iwa-mimo.
Iwa-mimo je iseda Olorun, ohun gbogbo nipa Olorun ni o ko jopo sinu iwa-mimo. Olorun ti pe gbogbo Kristieni ni
agbaye si igbe aye iwa-mimo nitori pe Olorun tikara Re je mimo, O si nfeki a je mimo pelu. Ipe yi kii se fun wa lati
yan nkan miran, sugbon o je ase kan gbogi ti ko yp enikeni sile ninu gbogbo onigbagbo. O je oro to se koko fun wa
ni gbogbo igba, kii se fun wa tele e nigba ti o ba ro wa Lorun nikan bikose nibi gbogbo, nigba gbogbo fun gbogbo
wa.
Awon ese Bibeli wonyi kun fun awon itoni lati gbe aye iwa-mimo ti Olorun npewa si.
• I Tesalonika 3:13 -"Ki o ba lefi okanyin bale ni ailabuku ninu iwa-mimo ".
• 1 Tesalonika 4:7 - "Nitori Olorun kope wafun iwa eeri, sugbonfun iwa-mimo."
• Efesu 4:24 -"Ki e si gbe okunrin tuntun ni wo, eyiti a da nipa ti Olorun ni ododo ati ni iwa-mimo otito ".
• Heberu 12:10 "Ki awa ba leje alabapin ninu iwa-mimo re ". Orin Dafidi 96:9 "Esin Olorun ninu ewa iwa-mimo
Re ".
BI ASE LE MU IGBE AYE IWAMIMO DAGBA (Oun tesiwaju lati ose ti o koja)
Ki a ba le dagba soke ninu igbe Iwa-mimo, a gbodo ko ise iwa-mimo ti anfi s'ojuse, awon si niwonyi:
5. O je iwa wiwa ni okan kan pelu Olorun. Eyi tumosi ife lati se ife Olorun ati nini ife tooto si gbogbo ona Re.

6. O je yiyera fun gbogbo ese ti o mo, ati gbigboran si gbogbo ofin Olorun ti o mo. Eyi nii se pelu bi o ti ndojuko ese

re ti o dun mo, ti o si mu lewu pupo fun igbe aye iwa-mimo. Se ohun ti Dafidi Se ninu Orin Dafidi 19:12-13.

7. O je nini igbe aye suuru ati ise ara eni. Eyi tumosi ilakaka lati pa awon ife ara, kikan eran ara mo agbelebu pelu

awon ifekufe re, fifi awon itara re si abe isakoso ati awon ife ti ara yii - Romu 6:12; Jakobu 3:2; Owe 16:32;

Danieli 1:8; Lefitiku 10:9; Romu 14:21.

8. O je nini ife ati lilo ife laarin awon ara – 1Tessalonika 4:9; Heberu 13:1 II Peteru 1:7-8. Eyi tumosi ikorira ati

kiko iwa aito ninu ohun gbogbo - ko si iro pipa, irenije, ailooto ninu iwa ati tabi lori oro owo ati bee bee lo.

O tumosi fifi awon aferi okan re si awon ohun ti mbe loke, gbigbe igbe aye re gege bi eniti isura re mbe ni orun ti o sin

la aye ja gege bi ajeji ati atipo - Matteu 6:19-21; Kolose 3:2; Heberu 11:10,13:14.

You might also like