Download as docx, pdf, or txt
Download as docx, pdf, or txt
You are on page 1of 14

Ose Ifa

Ogunda Oworin:

Okun kun nore nore


Osa kun legb-lebge
Ol'Owa nr'Owa
Alasan nr'Asan
Agba imole wo ehun oro, o ri pe ko sunwon
O gi irunmu d'imu yayaya
O gi irungbon di aya pen-pen-pen
D'ifa fun isese merin
Ti won nse olori oro n'Ife
"Nje, kinni a baa bo ni Ifa?"
Isese ni a ba bo, ki a to bo Orisa
Baba eni ni isese eni
Iya eni ni isese eni
Ori eni ni isese eni
Ikin eni ni isese eni
Odumare ni Isese
Isese, mo juba ki nto s'ebo

Òsé Ìretè
Òrúnmìlà ló dòràn èsè n sìsé
Èmi náà ló dòrò èbè n bíbè
Ifá ní bí Aláwòrò Ògún se Ògún
Bí ò tiè se Ògún
Kó móo rawó rasè
Yóó sì móo be Ògún
Ògún á sí móo gbó
Ògún a sì móo gbà
Òrúnmìlà ló dòràn èsè n sísè
Òrúnmìlà ló dòràn èsè n bíbè
Ifá ní bí Aléwòrò Obàtálá se Obàtálá
Bí ò tiè se Obàtálá
Kó móo rawó rasè
Yóó sì móo be Obàtálá
Obàtálá a sì móo gbó
Obàtálá a sì móo gbà
Òrúnmìlà ló dòràn èsè n sísè
Èmi náà ló dòrò èbè n bíbè
Ifá ní bí Adósù Sàngó se Sàngó
Bí ò tiè se Sàngó
Kó móo rawó rasè
Yóó sì móo be Sàngó
Sàngó a sì móo gbó
Sàngó a sì móo gbà
Òrúnmìlà ló dòràn èsè n sísè
Èmi náà ló dòrò èbè n bíbè
Ifá ní bí Akápò Òrúnmìlà se Òrúnmìlà
Bí ò tiè se Òrúnmìlà
Kó móo rawó rasè
Yóó sì móo be Òrúnmìlà
Òrúnmìlà lóun ó si móo gbó
Òrúnmìlà lóun ó si móo gbà
Èdú ìwo lo sòrò èbè
la fi wáá bè ó Ikin Alájogun
Elà kóo mó mó mò se kèbè
Bóorú bá mú
Abèbè níí bè é
Èbùré dé
Awo Olùjébè
Báa bá rawo rere
À á jébè
Òsé bèretè ó gbó
Eni eni
Kà sàì wáá beni ká gbà
Eni eni
Eji Ogbe
Ebiti ja faya lu'le
Dia fun Yeye Ale-ti-le
To feyin ti moju ekun sunrahun nire gbogbo
Nje Ale aje ki i le Awo
Eyin wa
Keni ma r'Edu pin o
Eyin wa
Ale aya ki i le Awo
Eyin wa
Keni ma r'Edu pin o
Eyin wa
Ale ire gbogbo ki i le Awo
Eyin wa
Keni ma r'Edu pin o
Eyin wa

2
Otoo-too-too
Oroo-roo-roo
Otooto laa ko’le
Otooto laa gbe’nu u re
Ogbon ta a fii ko’le
Ko to eyi taaa fii gbe’nu u re
Dia fun Orunmila
Nijo ti Ajogun merin ka won mo’le l’Otu Ife
Ti Baba le won, le won
Ti won o lo
Ebo ni won ni ko waa se
O gb’ebo, o ru’bo
E wa ba ni ni wowo ire gbogbo

Oyeku Meji
Opele loyo tan lo dakun dele
A difa peregede tii see ojumomo
Ojumo ire mo mi loni o
perengede o ni yeye ojumomo
Ojumo aje mo mi loni o
perengede o ni yeye ojumomo
Ojumo aya mo mi loni o
perengede o ni yeye ojumomo
Ojumo omo mo mi loni o
perengede o ni yeye ojumomo
Ojumo Ogbo Ato mo mi loni o
perengede o ni yeye ojumomo

Iwori Meji

Iwori Meji ayipo


Iwori Meji atẹpo
a lo difa fun Gọdọgbọ
eyi ti n gbogun re ilu Ilebe
Wọn lori rẹ ni o ba ṣe.
Ẹlẹda mi ba n ṣẹgun
kemi no da laje.
Ẹlẹda mi ba n ṣegun
kemi na donire gbogbo.

Odi Meji

A dín dí Òdí,
a dìn dì Òdí
a difa fun Eji Odi
ti o ma gbọrun di,
tifa o ma gbe ile aiye tu.
O ni bi ẹ ba ri ẹ ki gbe mi lọ,
aye Esuru ko iwọdo.
O ni bi ẹ ba ri ẹ ki gbe mi lọ,
aye Eminẹ wọlọ.
O ni bi ẹ ba ri ẹ ki gbe mi lọ,
eewọ oriṣa kan ti ẹ ni.
Epo ta ba fi dinkin,
kii wọ ikin ninu.
Irosun Meji

Irosun Meji owo oloko o to na


A dia fun Ọrunmila
Baba fi ọgẹdẹ agbagba gbọmọ rẹ kale lọwọku.
Ifa ni gbigbani o gba mi o,
Ọgẹdẹ agbagba kii gboloko ti.
Ọrunmila gbigba ni o gba mi.

Ọwọnrin Meji

Ọwọ n wo la pe lowo mi ni,


ọwọ n jẹ laa pe niyan
a difa fun eyi to wo ọmọba lẹhin ajọri o.
Tewe tagba ni re jo yio wọn,
ẹ sare wa, ẹ wa raja ọmọba.

O ṣe sare wa, ẹ wa raja ọmọba o


Ẹ sare wa, ẹ wa ra ọja ọmọba.
Atewe atagba ni raja ẹyi to wọn
Ẹ sare wa, ẹ wa raja ọmọba.
Ẹ sare wa, ẹ wa raja ọmọba o
Ẹ sare wa, ẹ wa raja ọmọba.
Atewe atagba ni raja ẹyi to wọn
Ẹ sare wa, ẹ wa raja ọmọba.

Ọbara Meji

O sẹ pẹlẹnjẹ ọwọ mi ọtun.


Ọ rọ minijọ ọwọ mi osi.
Abẹbẹ oje lo mu oju Ọlọja tutu ninini
a difa fun Ọba Ado,
Ejigbara ilẹkẹ
nijọto rire ba wọn mulẹ ibudo.
Ẹbọ nan ni o ṣe,
o si gbẹbọ nbẹ o rubọ.
Ẹru Ẹpo, ẹru Ọfa,
ẹ wa ba ni ni jẹbutu ire.
Jẹbutu ire laa ba ni lẹsẹ ọbariṣa.

O n ṣe ki lo ṣonibudo dọba?,
Eji Ọbara, Ifa lo ṣonibudo dọba.
Eji Ọbara, ki lo ṣonidubo dọba?
Eji Ọbaraaa, ori lo ṣonibudo dọba.

Ọkanran Meji

Ki iwo kan mi, kemi kan ọ,


Akanla lọkanran Meji kan ra wọn
A difa fun Adeṣọkan
Nijọ ti n ti n kọle ọrun bọ wa kọle aiye.
Ẹbọ ni wọn ni o ṣe,
O si gbẹbọ nbẹ, o rubọ.
Riru ẹbọ ni fin ti gbe ni.
Aitete ru teṣu a da ladanu.
Ko pẹ, ko jinna,
Ifa wa ba ni laarin iṣẹgun,
Aarin iṣẹgun la ba ni lẹsẹ ọbariṣa.
O n ṣe:
Ki lemi o ṣe la n temi
Owo n temi o ṣe la nifa
Ifa ni n o ṣe la ni temi
Owo n temi o ṣe

Ogunda Meji

Aguru maguda
aguru maguda
bi ida o ba sunwọn
eji apori ida ko to dagun
a dia fun Ọrunmila,
baba n lọ re gba dudu ranran
eyi ti ṣe ọmọ alaran oyigi.
Oṣo ni n ba n pe ori mi nibi.
Ẹ jọọ mi, ẹ ju ẹ, bi iṣẹ rẹ ba fọ,
wọn sin lẹhin Ṣango ni.
Bi babalawo ni n ba n pe ori mi nibi.
Ẹ jọọ mi, ẹ ju ẹ, babiku ba ku tan,
wọn sin lẹhin asẹ.
O lọkunrin, o lobinrin ni n ba peri mi nibi.
Ẹ jọọ mi, ẹ ju ẹ, Eṣu ni rẹhin ẹni to ri i.
Ifa lemi ni mo rẹhin awọn ọta mi.

Ọsa Meji

Isa n salubọ pẹrẹpẹwu


a difa fun agbẹ
eyi ti o ti le sa roko
eyi toko sa rele.
Ẹbọ ni wọn ni [k]o ṣe
o si gbẹbọ nbẹ, o rubọ
riru ẹbọ ni fi ti n gbe ni,
aitete ru teṣu a da ladanu
ko pẹ, ko jinna,
Ifa wa ba ni laarin iṣẹgun
aarin iṣẹgun, la ba ni lẹsẹ ọbariṣa.
Ta ba waiye, nṣe la ni gba.
Ifa jẹ [ki] n nigba rere.
Ẹlẹda mi ko gbe mi o
ki n nisimi.
Ba ba waiye ṣe la nisimi

Ika Meji

Eni Tere,
Eji Tere
a difa fun igbado
eyi ti n loko ailere lọdun.
Ẹbọ nan ni [k]o ṣe,
o si gbẹbọ nbẹ, o rubọ.
Asẹhin wa, asẹhin bọ,
igbado wa donigba aṣọ.
Asẹhin wa, asẹhin bọ,
igbado wa doni

Ọlọgbọn [Oturupọn] Meji

Mọgbọnmọgbọn kan ko ta koko omi mọ eti aṣọ


mọramọran kan o mọ yepẹ ilẹ
a difa fun Ọdunbaku
ọmọ Iwarẹrẹ nifẹ.
Nba ti iku desin oo,
ẹyọrọ logbadiẹ irana mi lọ.
Adiẹ irana ti mo gbelẹ wa da?
Ẹyọrọ ti gbe lọ

Otura Meji 1

Dagadamba n fura
ọsẹyẹ oko gbọ mọle
Aworokonjobi
a dia fun Ọrunmila.
Baba n lọ re gba gambi,
a gba gambi o, a gba a wa,
a le we lawani a gbe ede bọrun.
Ifa wa wa di mọle

Irẹtẹ Meji 2

Ajalu yeke
awo omi ni ṣawo omi.
Ajalu pẹtẹ
awo ẹẹrẹ ni ṣawo ẹẹrẹ.
Ajalu sorosan
lo difa fun kankan
eni ti n re aiye ainiku.
Won ni ki awon mẹtẹẹta o rubọ.
Ọmọ iya kan naa ni wọn.
Omi, ọ gbọ riru, o ru o; o gbọ titu, o tu.
Ko pẹ, ko jinna,
Ifa wa ba larin iṣẹgun.
Kankan gbọ riru, o ru o; o gbọ titu, o tu.
Ko pẹ, ko jinna,
Ifa wa ba larin iṣẹgun.
Ẹẹrẹ nikan ni n bẹ lẹhin ti o rubọ.

Ọsẹ Meji
Igba abidi jẹgi
arugbo eti emi,
atori abidi gbadagi
a dia fun Ọrunmila,
baba n ṣe awo rode Irọ.
Ifa jẹ [ki] ara o rọ mi,
akasu mẹfa nirọ fi rọ ni.
Ọrunmila jẹ [ki] ara o rọ mi

Ọrọgun [Ofun] Meji

Ifa nla la nla fi gbafa nla n la,


oogun nla nla laa figba oogun la nla.
Ẹgbasere laa fi tanran Sere.
Igba ta a ba ri Sere mọ,
emi la fi tanran ẹ gba a,
a difa fun Olokun
nijọ ti ẹri gbogbo n ba ṣọta.
O ṣe bọwọ fun Olokun, omi mo gbọ
Ẹ bọwọ fun Olokun.
Olokun lagba omi.
Olokun lagba omi, Olokun lagba omi.
Ẹri gbogbo, ẹri gbogbo ẹ bọwọ fun Olokun.
Olokun lagba omi.
Olokun lagba omi, Olokun lagba omi.
Ẹri gbogbo ẹ bọwọ fun Olokun.
Olokun lagba omi.

Ìrosùn Òbàrà
Ó ní ká níre lówó ò tó ká gbà kun
A dífá fún Tètèrègún
Èyí ti ń lợ rèé fi ató pợnmi ợlà fún Olókun
A pợnmi ợlà a ríre o
A pợnmi ợlà a ríre
Tètèrègún fató pợnmi ợlà
Ó là wálé
A pợnmi ợlà a ríre.
Owonrin Sogbe
Esu Pere jegede
Egba Pere jegede
Agbangban ni n oroko
Agbangban ni n arada
A difa fun Ologesa
Ti o koro leje tomo tomo
Nje eje koro a o kumo o
Igba lewe jogbo
Eje awa o sai koro

Otura Ori ire


Sosoro awo abata
Lo difa fun Olori ire apesin
Nijo to n ti kole orun bowa Ikole aye
Won ni ebo ni ki o se Ki o bo ori ire
O gbebo o rubo o bo ori
Sosoro ma de o awo abata
Eyin o mo pe Olori ire Apesin
Sosoro de awo abata
Sosoro ma de o awo abata
Olori ire Apesin
Obara Bogbe
Ikú yò ó
Àrùn yò ó Òtòntò Ìròkò
A díá fún won lóde Ìdó
Omo atanná wiriwiri lékú lo
Ikú ti n be nílé yìí kó derù kó móo lo
Òwìrìwìrì
A ó tanná Ifá ràn wón lára
Òwìrìwìrì
Àrùn ti n be nílé yìí kó derù kó móo lo
Òwìrìwìrì
A ó tanná Ifá ràn wón lára
Òwìrìwìrì
Òfò ti n be nílé yìí kó móo lo
Òwìrìwìrì
A ó tanná Ifá ràn wón lára
Òwìrìwìrì
Gbogbo Jogun ti n be nílé yìí kó derù kó móo lo

ODU IFA OBARA OGBE 

Ewure be ile wo abeke peru


Olu gbongbo tii meekan wole
A difa fun Iyami osoronga
Won n sawo rode ipokia
Ta lo da wa lisun taa fi n sawo
Iyami osororonga
Lo da wa losun taa fi n sawo
Iyami osoronga
Eje a kunle kobinrin,
obinrin lo bi wa kawaa to deniyan
Ogbe-Wo Ẹhin

Aṣiju wẹhin obinrin awo apo,


aṣiju wẹhin ọkunrin awo amọ,
igba elepo abẹhin manamana
a difa fun onile eti odo
eyi ti n mẹnuju ṣe rahun nitori ọmọ.
Ẹbọ ni wọn ni ko ṣe,
o si gbẹbọ nibẹ o rubọ.
Ko pẹ, ko jinna,
ẹyin awofa ọjọ bi ti n ṣẹ.
Ko pẹ, ko jinna,
Ifa wa ba ni ni jẹbutu ọmọ,
jẹbutu ọmọ laa ba ni lẹsẹ ọbariṣa.
Ẹ ba wa ki yeye o. Yeye o a fidẹ rẹmọ.
Ọṣun yeye o, a fidẹ rẹmọ.
Ẹ ba wa ki yeye o, a fidẹ rẹmọ.
Ọṣun

Ose Otura

Penpe lese’e tubu


Ala agemo ni o to gele
I ba to gele
Nba um rele lowe
Dia fun Awurela
Nijo to nlo s’ode Ijebu
Ebo ni won ni ko waa se
Won gb’ebo, won ru’bo
Apejin laa pe Oniru
Apejin laa pe Oniyo
Apejin laa pe Alata
Apejin apela laa pe Ose-Awurela n’Ijebu
Ose-Awurela, Awo ire ni o se

Bi mo duro ti wure
Ire mi ko saigba
Bi m obere ti mo wure
Ire mi ko saigba
Bi mo kunle ti mo wure
Ire mi ko saigba
Bi mo jokoo ti mo wure
Ire mi ko saigba
Bi mo dubule ti mo wure
Ire mi ko saigba
Obi
Èrín kèé
Òrìn sèsè
Dífá fún Koówè
Ó nlo pabì lógbà awo
Èrín kèé
Òrìn sèsè
L’aládé fi ngb’obì lówó awo
Ile tutu
Ona tutu
Tutu tutu laa ba ile Oluweri
A difa fun Oluweri mogbo ojo
Atojo ateerun
Ile Oluweri kii gbona
ILe o nii gbona mo wa o
Orogbo
Gbinrin aro, kìkì àjà gbohùn gbohùn
Dífá fún Òrúnmìlà
Baba nlo f'orógbó bá ikú mulè
bá àrùn mulè
Bá òfò mulè
bá ejó mulé
bá ibi gbogbo mulè
Baba kò ní rí ohun ibi gbogbo mó
Wón ní kó sá káalè ebo ní síse
Nje a f’orógbó bákú mulè àwa kòní kú mó
Gbinrin aro, kìkì àjà gbohùn gbohùn, gbinrin aro
A f’orógbó bárùn mulè, àwa kòní sàìsàn mó
Gbinrin aro, kìkì àjà gbohùn gbohùn
A f’orógbó bófò mulè, àwa kòní sòfò mó
Gbinrin aro, kìkì àjà gbohùn gbohùn, gbinrin aro
A f’orógbó bá ibi gbogbo mulè, àwa kòní
Rí ohun ibi gbogbo mó
Gbinrin aro, kìkì àjà gbohùn gbohùn, gbinrin aro
Omi
Alòló omí
Alòló omí
Ati-wáyè Igúnnugún
Ati-ròrun Akàlàmàgbó
Ón roni lójú tòki
Dià fún Orúnmílà
Ifá nlo rèé gbé olómi-tutu niyàwó
Ifá ló di èèwọ ifé
Erìgì-alọ ò níí fi olómi tùtù fùn ikú pa
T‫׳‬òun ikú ti di ìmùlé
Iyèrè Epo
[Gùrugùru guegue]…bis
D’ifá fun Epo
Tííí şe ọmọ iyá ẹbọ
Epo gorí rè ó d‫׳‬ẹbọ
Gùrugùru gùegùe
Epo gorí rè ó d‫׳‬ẹbọ
Gùrugùru gùegùe
Oro ibanujekan kiibaiyo
Òtúrà-Ìrètè - [Òtúrà-Itiyú]
Òtúrà lalèmu
Ìrètè lalèrá
Diá fún Arànìsán
Ti yóó mu igba otí kan àmu lòwó
Ọtí ọlà lawo n um

Iyo

 Ayǫyǫgo
Ayǫyǫgo
Ayǫyǫgo mango man
A difá fun Orunmila
Ifa nlo ree mu iyo yora
Awa ti amu iyo yora ǫrǫ ayo loba wa
Oro iba nu jȩ kan kii ba iyǫ

Oyin

 Okanran funfun ninini


A difa fun Oyin
Igba tit orun bo wáyè
Ȩbǫ ni wǫn ni ko se
O și gbebǫ nbȩ o rubǫ
Ruru ȩbǫ ruru atekȩșù
E wà ba ni jebutu rere
Njȩ a kii la oyin ka roju
Oro oyin kó si dun

Adiye /Akuko Ati Abo Adiye:


Akin ló yelé Ìja gìrìgìrì ló ye òde
Ìpàkó lòlòlò ni kò jé kómo awo réle Olófin lo rèé yin bo
Adífá fún Òrúnmìlà
Baba nlo gba obìnrin
Ikú Ikú gbó, ó gorí ìrókò
Ikú yowó agada ìgède ìgède
Wón fi Ewúré be Ikú, Ikú lóhun ò gbó
Wón fi Àgùtàn be Ikú, Ikú lóhun ò gbà
Njé Adiye Okòkó ni Ikú gbà, tí Ikú fi lo
Akin ló yelé
Ìja gìrìgìrì ló ye òde
Ìpàkó lòlòlò ni kò jé kómo awo réle Olófin lo rèé yin bo
Adífá fún Òrúnmìlà
Baba nlo gba obìnrin Àrùn
Àrùn gbó, ó gorí ìrókò
Àrùn yowó agada ìgède ìgède
Wón fi Ewúré be Àrùn, Àrùn lóhun ò gbó
Wón fi Àgùtàn be Àrùn, Àrùn lóhun ò gbà
Njé Adiye Okòkó ni Àrùn gbà, tí Àrùn fi lo
Akin ló yelé
Ìja gìrìgìrì ló ye òde
Ìpàkó lòlòlò ni kò jé kómo awo réle Olófin lo rèé yin bo
Adífá fún Òrúnmìlà
Baba nlo gba obìnrin Òfò
Òfò gbó, ó gorí ìrókò
Òfò yowó agada ìgède ìgède
Wón fi Ewúré be Òfò, Òfò lóhun ò gbó
Wón fi Àgùtàn be Òfò, Òfò lóhun ò gbà
Njé Adiye Okòkó ni Òfò gbà, tí Òfò fi lo
Akin ló yelé
Ìja gìrìgìrì ló ye òde
Ìpàkó lòlòlò ni kò jé kómo awo réle Olófin lo rèé yin bo
Adífá fún Òrúnmìlà
Baba nlo gba obìnrin Ejó
Ejó gbó, ó gorí ìrókò
Ejó yowó agada ìgède ìgède
Wón fi Ewúré be Ejó, Ejó lóhun ò gbó
Wón fi Àgùtàn be Ejó, Ejó lóhun ò gbà
Njé Adiye Okòkó ni Ejó gbà, tí Ejó fi lo
Akin ló yelé
Ìja gìrìgìrì ló ye òde
Ìpàkó lòlòlò ni kò jé kómo awo réle Olófin lo rèé yin bo
Adífá fún Òrúnmìlà
Baba nlo gba obìnrin gbogbo
Gbogbo gbó, ó gorí ìrókò
Gbogbo yowó agada ìgède ìgède
Wón fi Ewúré be gbogbo, gbogbo lóhun ò gbó
Wón fi Àgùtàn be gbogbo, gbogbo lóhun ò gbà
Njé Adiye Okòkó ni gbogbo gbà, tí gbogbo fi lo
Eye Etu
Emó ni réko tirè wélé wélé
A dífá fún Ìretè
Wón ní kó rúbo kó ba lè di eni àpésin
Wón ni kó rubo kó ba lè eni oba
Ó gbé ebo Ó rúbo
Ó gbé èrù Ó tèrù
Ó gbó kara ebo Ó haaa
Njé mo méye rúbo
Òrò mí di òrò èye, mo ti méye rúbo.
Ifá lo pa o
Emi ko mese iku eye
Ifá lo pa o
Ajalu Toro toro
Eje bale ibi Adero
Arubi ni seru ita
Eje bale ibi Adero
Alagbede kó ijise Ogun
Eje bale ibi Adero
Opon om ita ko ji se Osun
Eje bale ibi Adero
Esinsin to nba oderin yio ri edoki eran je
Eje bale ibi Adero
Eje bale ta soo soo
Eje bale ibi Adero Eje bale tasi Ifa lara

You might also like