Download as docx, pdf, or txt
Download as docx, pdf, or txt
You are on page 1of 5

OSe 1

Ojo: 16th April 2021

Eka Eko: jss2

Ise: Yoruba

Akole: Asa ogun jija laye atijo

Ogun je ohun ti o buru jojo nile Yoruba. Opolopo omo lo lo d alaini baba, ti opolopo ilu si tipase ogun di
ahoro. Apeere awon jagunjagun nile Yoruba ni Oranmiyan ti ilu oyo ati Owa obokun. Orisirisi ogun abele
lo ti sele nile Yoruba. Lara won ni Ogun ijaye ati ilu Ibadan, ogun kiriji eyi ti Ibadan ba awon ijesa ati Ekiti
ja, Ogun owiwi eyi ti awon Egba ba Ijebu ja, Ogun Ibadan ati ijebu, Ogun Egba pelu ota ati ogun ogun
modakeke ati ife.

Ohun ti o n fa ogun nile Yoruba

Awon ohun ti o ma n mu ki ogun jija be sile lawujo Yoruba, laye atijo ni a ti ri egun agbara awon
alagbara, aala ile, ife ati ko ni leru ti a tun n pen i onisunmomi ,yiyan ara eni je lori isakole, ilara ilu, bi
jagunjagun ko baa ni owo lowo abbl.

Ipalemo ogun

Oba alaafin lo ni ase lati sigun si ilu miran. Tabi oba ilu miiran tabi bale ibe. Ki won to se eyi, won yoo bi
ifa leere boya isigun oun ko ni ba ewu de. Won yoo sib o opagun. Leyin eyi ni awon eso awon omo ogun
yoo gbera lo soju ogun, ago ogun nii wo yoo lo loju ija. O sii seese ki ilu miran o tii ranse si ilu ti o ba wa
labe re fun n iranlowo ki won baa le rii omo ogun to too fun ija naa.

Awon jagunjagun

NI le Yoruba, Oye ti oba ma n fi da akoni jagunjagun lola ni oye “ Aare ona kakanfa” ko sis ii oba naa ti lee
yan kakanfo ayaafi Alaafin.Amo ti a ba n soro nipa orisirisi ipo awon omo ogun laye atijo nile Yoruba.
Balogun lo ni ipo ti o ga ju. naa ni awon isomogbe tire. Otun balogun, Osi balogun, Seriki ni ipo ti o tun
tele. Nigba ti asipa je ipo ti o tun tele. Nigba ti Asipa jeipo ti o kangun si ipo seriki. Leyi eyi nit i
sarumi(olori awon omo ogun ti o ma n fi esin ja). Aare ago, lara oye ni. Ani lati mo daju pe, labe awon
isori ijoye ogun yii, awon naa yoo ni omo ogun tii onikaluku won naa yoo sin ii ipo ti o di mu.

Eto ogun jija

Ni owoowo ni won maa n ja ogun ni oju ogun ni aye atijo. Owo otun ni awon otun ni awon otun balogun
yoo waa, owo osi Balogun nii osi Balogun gbodo wa. Nigba miran o lee je sarumi ni olori ogun elesin ni
yio bere ija, o da lori ase ti Balogun ba pa loju ogun ati iru ete ogun ti won ba fee lo.

Ami
Ni awon omo ogun ti n sise ajetelemuye. Awon ni a n pen i (spy) ni ede geesi. Won a mura bi ajeji lasan
wo inu ilu ti won fe kogun ja lati fi ogbon mo ipalemo de ogun ti n bo lona. Eyi yoo lee je kii won o moo
bi ota won se n mura de ogun naa. Eni tii ko laya, tii ko si gbon kii se iruu ise yii.

Yara

Eyi ni koto ti a gbe yi odi ilu ka ki o ma ba rorun fun ilu miran lati kogun ja ilu naa.Awon miran a moo pe
koto yii nii koto soja tori awon omo ogun a moo sapamo sibe ti ogun ba fee yiwo lati fii se aabo fun ara
won lowo ota ibon. Awon miran a moo gbe yara yii kii otao baa leerolu, ki lo lee seijamba fuun won.

Alore

Eyi ni awon omo ogun ti on so ibode ilu. Won a si ta ara ni olobo bi won ba keefin ijamba tabi ikolu ti o n
bo lona. Awon ni won mo nipa ti wole atijade eniyan ilu, won kii sii duro papo.

Alagbo

Alagbo je awon tii won moo n se itoju awon tii won ba fi ara gbe ogbe tabi ti nilo itoju ija. O le je okunrin
tabi obinrin.

Awon ohun elo ogun

Awon ni ofa, ibon, Ada, oko , kumo, Esin, ota, obe abbl

Ohun ti won maa je loju ogun

Awon ounje naa ni isu sisun, ewa yiyan,eran yiyan,guguru ati akara agbado. Bi awon ounje wonyi ba tan.
Awon omo ogun a maa piye loko oloko

Isagati

Orisirisi ona ni ilu kan le gba gbogun ti ilu miran. Won le sagati ilu kan ti won ko ba le kolu, ki won le
segun kiakia. Bi a ba sagati ilu kan, eyi ni pe a se awon ara ilu bee moo di won. Iya to ma n je awon ara
ilu ti a ba sagati ma n po pupo.

Irolu

Awon omo ogun ilu kan le ro lu ilu miran lojiji, ki won si segun ilu naa. O le je`loru ni won yoo rolu ilu
bee; o si le je osan gangan. Won si le rolu won ki won opada si ibudo ogun won.

Oju ogun

Bi awon omo ogun meji, to n ba ara won ja ba pade ara won ninu papa, owoowo ni won o ba ara won ja.
Bi owo kan b abo soju ija, won yoo maa lo gbogbo ohun ija ti won ban i lati fi ja. Bi won ba ja fun igba
die, owo keji yoo bo soju ija. Bi won ba ti n ja ni awon omo ogun to n fi esin ja yoo maa lo fin awon ota
won niran. Won yoo gesin wo rin awon ota.

Ipingun ati ofisn ogun jija


Gbogbo ohun ti a bari ko logun ni a n pen i ikogun. Odo Balogun ni awon omo ogun yoo da gbogbo re jo
si. Oba ilu to segun lo nii. Sugbon idaji re ni won yoo ko fun balogun. Ninu idaji to ba kan Baogun ni oun
naa yoo da si ona meji. Ona kan ninu re ni tire patapata. Idaji keji ni awon ogun iyoku yoo pin laarin ara
won. Won a si mu awon oloye ogun ti won segun leru. Sugbon won le pa oloye to ba dale tabi se ese
Pataki. Apeere ni Maye nigba ti awon Ibadan mu un leru ni ogun Erunmu nitori pe oun lo da ogun naa
sile.

Ise amurele:
1. Salaye ona marun un ti a le fi dena ogun jija ni awujo wa.
Ose: 1

Ojo: 2nd April 2020

Eka Eko: jss1

Akole: Asa igbeyawo nile Yoruba

Igbeyawo ni isopo laarin okunrin ati obinrin ti o ti balaga, lati jo maa po gege bi okoati aya. Ni ile Yoruba
paapaa laye atijo, awon Yoruba kii fi owo yepere mu igbeyawo rara.

Idi ti okunrin fi n gbe obinrin niyawo ki obinrin le je oluranlowo fun un. Oluranlowo ni obinrin je fokunrin
ninu ile, ninu ebi, lenu ise ati ni gbogbo ona ti eniyan le ronu kan. B e gege ni okunrin naa je oluranlowo
ati alasiri fobinrin.

Lona keji, okunrin ati obinrin n fe ara won ki won baa le ni aaro nile. Omo ni iyi, omo ni eye igbeyawo.
Laye atiijo ati titi di oni yii, Igbeyawo ti ko ban i omo ninu fori sanpon.

Eto ati ilana igbeyawo ni aye atijo

1. Ifojusode: Ifojusode maa n waye nigba tie bi kan ba n wa iyawo fun omo won ti o ti balaga.
2.
3. Iwadii: Awon ebi omokunrin yoo beere sii se iwadii nipa idile ti won ti fe fe obinrin nitori pe
orisirisi idile lo wa idile miran arun buburu a maa yo won lenu bi apeere arun aganna, warapa,
abisinwin abbl. Idile miiran won kii dagba, won yoo tun tesiwaju lati se iwadii iru eniyan ti
omobinrin naa je boya oni kebekebe ni, leyin eyi ni won yoo lo beere lowo ifa gege bi Eleru-ipin
ti ko lee puro, gbogbo asiri ojo ola igbeyawo naa ni yoo han kedere lodo ifa.
4.
5. Alarina: Alarina je okunrin tabi obinrin ti o sunmo obinri, o le je molebi obinrin, o le je ore tabi
molebi obinrin oun ni eni ti o n ye ona fun omokunrin ti o fe fe iyawo ki awon ebi mejeeji to
pade.
6.
7. Isihun: Isihun ni gbigbo ati gbigba ti omobinrin gba lati je ki omokunrin naa je afesona oun.
Omokunrin yii yoo san owo isihun fun awon ebi omobinrin yii ki o to le ma aba omobinrin naa
soro, owo naa je oke kanfun laye atijo won yoo si fi obi abata, ataare ati orogbo si owo isihun
naa.
8.
9. Itoro: Awon obi ati die ninu ebi omokunrin yoo lo si ile obi omobinrin lati so fun won pea won
nife si omo won obinrin lati fe. Awon obi obinrin yii yoo dajo fun awon ebi omokunrin pe ki won
pada wa, o le je leyin ojo meje tabi ju bee lo, awon ebi omobinrin yii naa yoo le se iwadii lowo
bi ojo iwaju igbeyawo naa se ri, ti iwadii won ba yori si ire, gbigbo ati gbigba ti awon obi
omobinrin gba lati fi omo won obinrin gba lati fi omo won obinrin yii gege bi aya ni awon Yoruba
n pen i baba gbo iya gbo. Awon ohun ti a fi n sadura ni obi, orogbo, ataare, oyin, aadun, oti ati
awon ohun miran to jemo iwure lona tiyawo.
10. Idana: Idana se Pataki ninu eto igbeyawo abinibi. Oun lo kangun si igbeyawo gan-an. A ko le se
igbeyawo laise idana. Awon ohun ti a fi n dana ni: obi ogoji, ataare ogoji, orogbo ogoji, oyin,
aadun, oti igo meta, owo, owo ori iyawo,(eyi ko lopin, bi iyawo bat i tobi to lowo oko re ni oko re
yoo se san owo lee lori). Lara awon nkan miran isu ogoji, iyo apo kan, ika eja aro, a so orisirisi.
Ojo ti a saaba ma n je ojo iyi ati ojo eye.Ojo ti a ma n se ayeye yii ni ojo aje,ojo ojobo, ojo
abameta tabi ojo Aiku. A kii saaba se iru ayeye bayii ni ojoru.

Ise amurele
Daruko orisirisi igbeyawo ti o wa laye ode oni, ki si salaye lekunerere

You might also like