Download as docx, pdf, or txt
Download as docx, pdf, or txt
You are on page 1of 4

Deeti: 18th April

Akole: Asa isomoloruko nile Yoruba

Kilaasi: JSS2

Yoruba bo won ni ile laa wo ka to somo loruko. Isele to n ba sele lagbo ile ti a ti bimo tabi ona ti omo ba
gba waye maa n se atokun oruko ti a o soo. Bakan naa ni ibi ti a bi omo si ati asiko, ojo, esin abbl. Lo ma
n niise pelu ouko ti a o so omo ni ile Yoruba.

Eto isomoloruko

Ki o to di ojo isomoloruko, orisirisi oruko ni a maa n pe omo titun ti a sese bi. Awon miran a maa pee ni
alejo nitori pe won ka a si alejo, ikoko, tunfulu tabi arobo. Ni idile olu oje,onigbeeti, oluokun-esin, aresa,
onikoyi ati olugbon, ojo keje ni a n n so omobinrin keje ni a so won loruko. Sugbon ti won ba je
omokunrin ojo kesan-an ni a n so loruko. Ti okan ninu won ba je okunrin, ti ekeji si je obinrin ojo kejo ni
ao so won loruko. Ojo isomoloruko ni idile olofa tun yato, ojo keje ni a nso omokunrin loruko, ojo karun-
un nit i omobinrin. Sugbon ti won ba je ibeji okunrin ojo keje nit i okunrin, ti ibeji obinrin ojo karun-un.
Ni idie Alaafin, ojo kefa ni a n so omoloruko.

Alaye nipa iru awon omo wonyi

Omo ti o mu ese waye n-i ige

Omo ti o ni ika mefa ni- olugbodi

Omo ti a bi soju ona ni- abiona

Omo ti a bi nigba ti baba re ko si nile- bidemi

Omo ti irun ori re takoko ni- dada

Omo ti o wa ninu apo nigba ti a bii ni- oke

Omo ti o gbe ibi ko orun waye ni- ojo/aina

Omo meji ti a bi leekan naa ni – Taiwo/kehinde

Ta ni alaba?(Omo ti a bi le idowu)

Omo ti baba re kun i kete ti a bii tan ni- babarimisa

Omo ti o kere pupo nigba ti a bii ni-kiyeseni

Omo ti a n pen i kasimaawo tabi aja ni – abiku omo

Omo ti a n pen i ilori ni- Omo ti iya re ko se nnkan osu ti o fi bi I leyin ti o de ile oko

Bawo ni a n se n fi awon nnkan wonyi se adura nibi isomoloruko


Aadun- ki aye omo naa ladun

Oyin- ki aye omo naa loyun

Ataare- ki aye maa soro re nire, ko sin omo pupo bi ataare

Orogbo- ko dagba, ka dogbo

Obi- ki obi bi iku ati arun danu

Eja gbigbe: otutu kii meja lale odo, aye ko nii gbona moo

Eku gbigbe: ki eku maa ke bi eku, ki eye maa ke bi eye, ki aye re maa lo daadaa

Ireke: adun niti ireke ki aye re ladun

Omi- ki aye mase ba omo tuntun naa se ota, nitori pe a kii ba omi sota

Oti- aye omo tuntun naa ko gbodo ti

Owo-Owo niyi, lagbaja. Oun ni a n na laye. Ki o rowo saye

Ipo ti e bi wa nigba ti a bi omo

Ara ohun ti a ma n wo ki a to so omo loruko ni ipo tabi aye ti omo loruko ni ipo tabi aye ti ebi baba ati
iya re wa nigba ti a bii. Iru oruko bee ni eyi ti a npe ni oruko abiso ti kii se pe omo mu bo latorun. Bi
apeere e je ki a wo oruko alaye ti itumo

(a) Oruko to n fi ipo ebi ati asiko han

1. Mosebolatan: Bibi omo yii fi han pe ireti ola ti ebi, ko tii pin

2. Fijabi: Omo tie bi ja si ki a to bii tabi ti a bi ni asiko ti ija wa ninu ebi

3. kumolu: Oruko omo ti bi leyin ti iku mu olu tabi olori ebi lo

4.Onikeepe: Omo ti a bi sinu ebi pupo, ti won yoo maa ke e. Ese ebi pe lati kee

5. Ibiyimika: Omo ti a bi ni asiko tie bi yii k lotun-un losi

(b) Omo ti a bi si idile oye

Oruko oye ti obinrin n je: Oyebola, Oyewumi, Oyekemi, Oyetooke, Oyebanke

Oruko oye ti okunrin n je: Oyebade,Oyediran,Oyeyemi, Oyebiyi, Oyelekan

(d) Omo ti a bi si idile oba alade

Oruko ti obinrin le je: Adedoja, Adepele, Adeninhun, Faderera


Oruko ti okunrin le je: Gbadegesin, Adeyemo, Adeyemi,Adedigba,Adeniran

(e)Omo ti a bi ni idile ola

Oruko eyi ti okunrin n je: Olayemi, Olawuwo,Olaonipekun

Oruko ti eyi obnrin n je: Olapeju, Oladiran, Oladunjoye

2. Sise akiyesi ojo ati asiko ti a bi omo: E je ka wo oruko pelu alaye ati itumo

1. Odunjo, Odun-ifa,Odunayo: Omokunrin ti a bi lasiko odun ifa

2. Babajide/Babatunde: Omokunrin ti a bi ni kete ti baba baba re ku

3.Babarinde/Babawande: iru oruko yii fi igbagbo Yoruba ninu ajinde mule

4.Yerimisa/johojo: Omobinrin ti a bi iya re si ku lojo naa tabi ki a to so omo naa loruko

3. Oruko to jemo esin

Oruko awon omo ti a bi si idile ogun: Ogunbunmi, ogunlana,Esubiyi, sangobunmi

Idile olorisa nla: Orisatola,Saseyi,Orisarinu, Olorisade

Ifa: Fabunmi, Fatola, Faleti, Fafunke, Fakemi

Egungun: Olojeede, Eegunnikee, Eegunjobi,Ojetola

Esu: Esuleke, Esubunmi, Eesutosins

Oruko abiku to n fi igbagbo Yoruba nipa Ajinde ati Aseyinwawo

1. Apaara: Eni to n lo, to n bo nigba gbogbo


2. Enilolobo: Eni to lo, lo tun pade bo
3. Omotunde: omo ti o ku tun de
Oruko to le ko itiju ba Abiku: Oku, aja, akuji

Ise amurele

Ko alaye tabi itumi awon oruko wonyI

Olugbodi

Oni

Omope
Aasa

Ola

Otunla

1. So oriki obinrin marun-un, ki o si so oriki okunrin marun-un


2. So oruko abiku marun-un ati oruko ogun marun-un

You might also like