Download as docx, pdf, or txt
Download as docx, pdf, or txt
You are on page 1of 2

ORIKI EGUNGUN

Eégún Bàbá mi òfe o,


Òòsà Bàbá mi òfe,
Eégún yìí ma le tété.
Ó mà dàbí osù.
Onígborí omo kúlódò.
Omo kúlódò awubi.
Omo kúlódò awusi èyò.
Omo ikú kan tí mbe lódò tó tì ìgbórí wá.
Taa ní nso pé Onigbòrí kò lódò.
Wípé omi ikú ni wón ńpon.
Ta lóni Àasà.
Ta lóni Ękoro.
Ta lóni dòbòdé omi ìpakùn.
Ta lóni afúnlété omi ayaba.
Dòbòdé ò demi lórun ęsè mó.
E wo afúnlété bó ti ntú ayaba láso.
Èrò Ìgbórí omo kúlódò awubi.
Ará Ìgbòrí omo kúlódò awusi èyò.
Onígbórí won ò lagba.
Gbogbo won ní ńjé baba.
Omo Ajé baba maję arúgbó.
Ará Ìgbòrí e kú ma ko apinni.
Níbi o ko ìdí rę si.
Níbi o ko ìdí rę lo.
Ęni arakan tii jijo awo.
Omo arùku rojà ma tà.
Òkú ta gbe rojà tí ò tà.
A gbé òkú òhún padà wálé.
O wá yóyó ó ku bi okinni.
Okinni náà wá ńbe léyìn Òòsà Akire.
Òun ni Molufon fi nse iwín bo.
Ará Igbori omo Isin lojude ìjan.
Osan rèrèrè lójúde Ìwòyè.

My father Egungun: Ofe o.  The deity of my father ofe.  This masquerade is


beautiful.  It is beautiful as a new moon.  Onigbori, son of Kulodo.  The
son of Kulodo Awusi.  The son of Kulodo Awusi eyo.  The son of one
strong personality (the spirit of the dead) at the brook who came from
Igbori.  Who says that Onigbori has no brook?  That says they drink from
the water of death?  Who owns Aasa River?  Who owns Ekoro River?
Who owns Dobode, water of Ipakun?  Who owns the clear water, the brook
of the Queen?  Dobode River is now only a few inches deep.  Look at how
the clean brook is also stripping the Queen naked.  Dweller of Igbori, the
offsprings of Kulodo Awusi.  Citizens of Igbori, the offspring of Kulodo
Awusi eyo.  People says that the people of Igbori have no elders.
Everybody now proclaims himself or herself as the most senior.  All of
them are called fathers.  They are called fathers yet they are not aged.  The
son of those that carried a corpse to the market for sale but nobody bought.
The corpse that was taken to the market for sale but nobody bought.  The
corpse was carried back home.  It began to dissolve gradually.  Until it was
reduced to the size of a needle.  The remains is now at the shrine of Orisa
Akire.  It is this remains that the children of Molufo ade worship as their
deity.

You might also like