Download as docx, pdf, or txt
Download as docx, pdf, or txt
You are on page 1of 9

EDE YORUBA

FONOLOJI ATI GIRAMA YORUBA

1. Oro-oruko wo lo gba eyan ninu gbolohun yii: ‘Awon olowo ni iya Ojo feran’? (a) Ojo (b) awon (d) iya (e) olowo
2. Toka si oro-oruko to n se ise oluwa ninu gbolohun yii: ‘Olu lo is oko ana iya Ojo’. (a) ana (b) Olu (d) Ojo (e) oko
3. Fa oro-oruko to n sise oro-apejuwe yo ninu: ‘Baba pe Akin alapata dudu ni aaro’. (a) Baba (b) aaro (d) alapata (e)
Akin
4. Aropo-oruko wo lo sise abo ninu gbolohun yii: ‘Won tete ranse si mi’? (a) mi (b) ranse (d) won (e) si
5. Toka si aropo-oruko eniketa to n sise oluwa ninu gbolohun yii: ‘O ranse pe won, bi a se n soro’. (a) won (b) pe (d) o
(e) n
6. Ewo ni oro-aropo afarajoruko to n se ise oro-apejuwe ninu: ‘Emi ni mo fun un ni iwe awa akekoo’? (a) un (b) Emi (d)
mo (e) awa
7. Toka si eyi ti ki i se oro-aropo-afarajoruko (a) oun (b) won (d) emi (e) awa
8. Ewo ni ki i se ooto ninu awon wonyi? (a) Oro-oruko le se ise oluwa ninu gbolohun (b) Oro-aropo-afarajoruko ni liana
eni ti nonba (d) Aropo-oruko le se ise abo ninu gbolohun (e) Oro-oruko miiran le yan aropo-oruko
9. Toka si oro-aropo-afarajoruko ninu gbolohun yii: Eyin omugo lo kun inu ile yii (a) Eyin (b) inu (d) yii (e) kun
10. Ewo ni ooto ninu gbolohun wonyi? (a) A le dunnu mo aropo-oruko (b) Oro-oruko ni liana eni ati nonba (d) Oro-
aropo-afarajoruko ki i gba eyan (e) Oro-aropo-afarajoruko le dipo oro-oruko ninu gbolohun
11. Aropo-oruko eni keji olopo eni to n sise eyan ni __________. (a) won (b) wa (d) yin (e) A
12. Toka si aropo-afarajoruko eni keta eleyo eni (a) Oun (b) Eyin (d) Awa (e) Iwo
13. Fa oro-ise kikun yo ninu gbolohun yii: ‘Mo moomo fe ran Olu si oko ni’. (a) fe (b) moomo (d) si (e) ran
14. Ewo ni ki i se otito ninu awon gbolohun wonyi: (a) Oro-ise kikun meji le jeyo ninu gbolohun kan naa (b) Asaaju oro-
ise le da jeyo, ko si ni itumo ninu gbolohun (d) Oro-ise agbabo ko le jeyo laini abo ninu gbolohun (e) Oro-ise elela se
e fi or obo ni aarin
15. Toka si oro-ise alailela (a) bawi (b) Gbagbo (d) reje (e) jade
16. Toka si eyi ti ki i se oro-ise kikun: (a) wa (b) si (d) sun (e) ri
17. Ewo ninu iwonyi ni a fi n so gbolohun po? (a) sugbon (b) oun (d) ayafi (e) ati
18. Ewo ni a ko le fi so oro-oruko meji po? (a) oun (b) anbosi (d) tabi (e) amo
19. Ewo ni a le fi oro-asopo ninu awon wonyi? (a) Gbolohun (b) Oro-oruko (d) Apola-aponle (e) Aropo-oruko
20. ___________ ni oro-aponle n ba sise ninu gbolohun (a) Oro-asopo (b) Oro-ise (d) Oro-oruko (e) Oro-eyan
21. Ewo ni apola oro-oruko ninu gbolohun yii: ‘Jide Alaba alagbede ni o de’? (a) Alaba alagbede (b) alagbede ni o de (d)
ni o de (e) Jide Alaba alagbede
22. Fa apola oro-ise yo ninu gbolohun yii: ‘A lo si odo baba’(a) A lo (b) lo si odo baba (d) si odo baba (e) lo si
23. Toka si olori awe-gbolohun ninu: ‘Gbogbo aye gbo pe Omobola ti loko’. (a) Gbogbo aye gbo pe (b) pe Omobola ti
loko (d) gbo pe Omobola ti loko (e) Gbogbo aye gbo
24. Fa awe-gbolohun afarahe yo ninu gbolohun yii: ‘Aso ti mo ran wu mi’. (a) ti mo ran (b) mo ran (d) Aso ti mo ran (e)
wu mi
25. Ewo ni gbolohun olopo oro-ise? (a) Ojo yoo ro ni irole (b) Tope rin kiakia (d) Aso yen dara (e) Titi rin de ile
26. Toka si gbolohun ibeere. (a) A o gbodo gbagbe (b) Igba wo ni a o lo (d) Inu re dun (e) Jowo ma gbagbe mi
27. Ewo ni oro ti aranmo ti waye ninu awon wonyi? (a) Kayode (b) sise (d) araalu (e) itupale
28. Ewo lo tona ninu bi a se pin oro yii – ‘tannganran’ si silebu? (a) ta-nn-g-an-r-an (b) tan-ngan-ran (d) ta-n-ngan-r-a-n
(e) tan-n-gan-ran
29. Bi faweli akoko ninu oro onisilebu meji ba je ‘e’ ewo ni ko le duro ni ipo faweli keji? (a) a (b) i (d) u (e) e
30. Akamo wo ni a n lo fun ilana adako fonetiki? (a) / ) (b) [ ] (d) ( ) (e) / /
31. Agbondo isale ni a ti n ri _________. (a) afase (b) erigi (d) olele (e) ahon
32. Ewo ni iro akunyun ninu awon wonyi? (a) [b] (b) [t] (d) [f] (e) [k]
33. Toka si oro ti ko ni faweli aranmupe ninu (a) okan (b) iyen (d) igbo (e) agbon
34. Faweli wo ni ko le bere oro Yoruba ajumolo? (a) [i] (b) [e] (d) [a] (e) [u]
35. Faweli wo ni ahanudiepe ninu awon wonyi? (a) [i] (b) [e] (d) [u] (e) [a]
36. Faweli wo ni a se ete roboto pe ninu awon wonyi? (a) [ᴐ] (b) [e] (d) [u] (e) [a]
37. ____________ ni konsonanti aferigipe. (a) [f] (b) [d] (d) [w] (e) [k]
38. Konsonanti afunnupe ni ________. (a) [r] (b) [n] (d) [f] (e) [b]
39. ____________ ni konsonanti arehon. (a) [t] (b) [h] (d) [m] (e) [r]
40. Akamo __________ ni a n lo fun adako fonemiki. (a) [ ] (b) ( ) (d) \ / (e) / /
41. Ewo ni ki i se konsonanti afetepe ninu awon iro wonyi? (a) [t] (b) [kp] (d) [gb] (e) [b]
42. ___________ ni konsonanti afeyinfetepe ninu awon iro wonyi: (a) [b] (b) [m] (d) [kp] (e) [f]
43. Ewo ni ki i se iro afunnupe ninu awon iro wonyi? (a) [f] (b) [h] (d) [s] (e) [t]
44. ____________ ni konsonanti aranmupe ninu awon iro wonyi (a) [r] (b) [n] (d) [b] (e) [d]
45. Ewo ni ki i se konsonanti aferigipe ninu awon iro wonyi? (a) [t] (b) [d] (d) [l] (e) [f]
46. _________ ni ki i se iro akunyun ninu iro konsonanti yii: (a) [b] (b) [r] (d) [w] (e) [k]
47. Nnkan __________ ni a papo se apejuwe iro konsonanti (a) meji (b) meta (d) merin (e) marun-un
48. Ewo ni ki i se faweli eyin ninu awon iro faweli yii? (a) [u] (b) [e] (d) [ᴐ] (e) [o]
49. Ewo ni o yato si faweli iwaju ninu awon iro faweli yii? (a) [i] (b) [e] (d) [e] (e) [o]
50. Ewo ni ko ba ofin ohun mu ninu awon oro wonyi? (a) igba (b) igba (d) igba (e) igba
LITIRESO YORUBA

1. Ewo ninu awon ewi alohun yii ni ko jemo esin kan pato? (a) Ijala (b) Esa (d) Ese Ifa (e) Rara
2. Ninu awon ewi alohun wonyi, eyi ti o jemo Orunmila Bara Agbonni-regun ni ___________. (a) Ijala (b) Olele (d) Iyere
(e)Rara
3. ____________ ni elere ibile to maa n ja awon asebaje ni pasan oro. (a) Etiyeri (b) Asunjala (d) Asunrara (e) Apesango
4. Inu ewi alohun wo ni a ti le ba oro idagbere, iwure, oriki-orile, oro to da lori ibagbepo laarin oko ati aya, oro to jemo
omo ati oro iwuri pade? (a) Esa-Eegun (b) Ekun iyawo (d) Ese-Ifa (e) Oya pipe
5. Awon ewi to je pe ko si ibi ayeye ti won ki i ti lo won ni ________. (a) ese Ifa, ijala ati esa (b) Oya-pipe, Esu-pipe ati
Sango-pipe (d) ofo, ogede ati ayajo (e) rara, ege ati dadakuada
6. ____________ je ona Pataki kan ti awon Yoruba n gba ko omo won ni iwa omoluabi laye atijo. (a) Sisun iyere (b)
Sisun ijala (d) Pipa alo apagbe (e) Pipa esa
7. Ori igun ko deede pa, eyin ijapa ko deede ri gbakagbaka. Iru itan to n so ohun to fa sababi eyi ni a n pe ni
___________. (a) itan isedale (b) itan ogun (d) itan agba (e) itan idi abajo
8. Ewo ni itandowe ninu awon itan yii? (a) Itan Ijapa ati Okere (b) Eebu alo ni ti ahun, ti abo ni ti ana re (d) Iroko Oba so
(e) Itan Ijapa ati Elede
9. ‘Mo bu mo-on’ ni ibere ___________. (a) Aro jija (b) Alo apagbe (d) Itan isedale (e) Itan ogun
10. Ni akoko ti ede-aiyede ba wa laarin eni meji, ti awon eniyan ba n pari re fun won ni itan __________ maa n waye. (a)
isedale (b) ogun (d) alo (e) agba
11. Ibo ni ere-onise ti maa n waye ninu litireso alohun? (a) Ibi ti won ti n pari ija (b) Odun ibile ati oniruuru ayeye (d) Ibi
jije ati mimu (e) Ibi ti a ti n kore oko
12. Ohun elo ti won maa n lo to duro fun apeere ogbo ninu eto isomoloruko ni __________. (a) oyin (b) obi (d) orogbo
(e) eja
13. Ewi apileko yato si ewi alohun nipa wi pe akewi yoo koko ___________. (a) gbo o, ki o to maa ke e (b) ri i , ki o to
maa ke e (d) ko o sile, ki o to maa ke e (e) ko o sori, ki o to maa ke e
14. Ohun ti o maa n ta akewi ji lati ko ewi apileko ni __________. (a) imisi (b) ife (d) owo (e) agbara
15. Ohun __________ ni Toyosi Arigbabuwo n lo lati fi kewi apileko re. (a) Esu-pipe (b) Oya-pipe (d) Sango-pipe (e) Ekun-
iyawo
16. Itan __________ wopo ninu awon iwe itan-aroso apileko D.O. Fagunwa. (a) ogun (b) meriiiiri (d) isedale (e) itandowe
17. Ta ni ki i se onkowe ewi apileko ninu awon eniyan wonyi? (a) Kola Akinlade (b) Tubosun Oladapo (d) Lanrewaju
Adepoju (e) Adebayo Faleti
18. Ere-Onise ti Duro Ladiipo se ti o pada di iwe ere-onitan ni ____________. (a) Basorun Gaa (b) Abiku Soloogun Deke
(d) Oba ko so (e) Lisabi Agbongbo Akala
19. Akopa ti gbogbo ohun ti o sele ninu itan apileko rom o ti o je-opomulero itan, ti itan tori re bere, ti o si ti ori re pari ni
a n pe ni (a) olori itan (b) ahunpo itan (d) apase itan (e) olu-eda-itan
20. Iru ere-onitan wo ni a n pe ere to bere pelu erin ati ayo sugbon ti gbogbo nnkan yi biri leekan naa, ti eni to je akoni
inu ere naa ti wa ninu erin ati ayo tele wa di eni ikaanu? (a) Erindekun (b) Ekunderin (d) Ladojude (e) Amerin-in-wa
21. Abere ki i kohun aso
Konko ki i kohun odo:
Sango ki i kohun orogbo
Eya ewi alohun wo ni eyi? (a) Rara (b) Ijala (d) Olele (e) Ofo
22. Alo baba mi kan laelae
Alo baba mi kan laelae:
‘Laelae’ ati ‘laelae’ je apeere ___________. (a) didogba (b) ifohungbohun (d) asoregee (e) ifohunpeniyan
23. Omo feni sepo lo n biresa ninu:
Omo sare bepo fun mi lo ya Mode lara.
Awon ila yii fi han pe ise ____________ ni iran Aresa maa n se: (a) abuwe (b) ebu (d) epo (e) agbede
24. Ise irin ati ohun elo irin ni i se pelu orisa _________. (a) Ogun (b) Obatala (d) Oya (e) Sango
25. Ewo ni ko jemo orisa odo ninu awon wonyi? (a) Oya (b) Osun (d) Yemoja (e) Oro
26. Nigba ti Ege wopo laarin Egba, _________ wopo laarin Oyo-Yoruba. (a) Olele (b) Alamo (d) Bolojo (e) Rara
27. Iran Olu-Oje ko gbodo je __________. (a) eku ago (b) eye ega (d) eran agbo (e) ejo ojola
28. Ewo ni eewo Esu? (a) Epo (b) Adi (d) Omi (e) Ori
29. Oku ko moye ti won n ra __________. (a) eku (b) aso (d) osun (e) ago
30. Eegun alare ni awon eegun to maa n _________. (a) korin (b) sawada (d) pidan (e) wo eku
31. Itan meriiiiri ni itan-aroso __________. (a) Debo Awe (b) D.O. Fagunwa (d) Kola Akinlade (e) I.O. Delani
32. Baba, baba, mo n lo niyi o:
Iya, iya, mo n lo niyi o
Ki n lowo, ki n bimo
Atofo, atarun ko ma wole to mi
Omo ni ki n gbe wale
Eya ewi alohun wo ni ewi yii? (a) Ege (b) Ekun-iyawo (d) Alamo (e) Sango-pipe
33. O di kanrin kese:
O darinnako
O doju ala
Bo o ba dorun
O sorun ‘re
Ma jokun
Ma ma jekolo
Ohun ti won ba n je lalade orun
Ni o ma aba won je
Eya ewi alohun wo ni eyi? (a) Obatala-pipe (b) Oro-pipe (d) Sango-pipe (e) Oku-pipe
34. Obinrin wo lo letoo lati moa wo egungun? (a) Ato (b) Amusan-an (d) Abore (e) Iyaloosa
35. Ogbo orogbo ni ki n gbo:
Ki n ma gbogbo obi
Orogbo ni i gbo ni saye
Obi ni i bi won sorun…
Ninu ______________ ni eyi ti wopo. (a) alo apagbe (b) iyere-Ifa (d) oriki-orile (e) ijala
36. O n yin alawo re:
Alawo re n yinfa
Enu to ya koto
Orin aw obo si i lenu
Ese to na fa a, ijo lo n jo
Ninu _____________ ni ewi yii ti jeyo. (a) Orin Obitun (b) Orin Alamo (d) Bolojo (e) Ese Ifa
37. Ewo ni ki i sara owo ewi alohun yii? (a) Ijala (b) Ege (d) Alamo (e) Olele
38. __________ ki i se ara owo ewi alohun yii. (a) Ijala (b) Esa-Eegun (d) Oriki Orile (e) Ege
39. Ewo lo yato ninu awon ewi alohun yii? (a) Ijala (b) Sango-pipe (d) Rara (e) Esa-Eegun
40. Bi Olele se je ti Ijesa, bee ni __________ je ti Egbado. (a) Gelede (b) Bolojo (d) Rara (e) Alamo
41. Ewo ni ki i se ewi alohun ti a fi n kilo iwa ibaje lawuju? (a) Etiyeri (b) Dadakuada (d) Bolojo (e) Ofo
42. Ewo ni ko si ninu alo apagbe ninu iwonyi? (a) Orin lile (b) Orin gbigbe (d) Ija jija (e) Ogbon kiko
43. Ewi alohun oriki-orile ki i so nipa ___________ awon ara atijo. (a) ogbon (b) ise (d) iwa (e) esin
44. Awon wo ni ki i sun Ijala? (a) Ode (b) Alagbede (d) Oloola (e) Babalawo
45. Ewo ni ki i se ooto ninu eyi? Awon egbe ere-onise ode-oni a maa sere ninu ________. (a) igbo igbale (b) telifisan (d)
gbongan (e) fiimu
46. Iran Alapa ki i je _________. (a) igala (b) eku ago (d) okete (e) ejo
47. Litireso apileko ki i __________. (a) ja ni laya (b) pa ni lerin-in (d) ko ni logbon (e) ko ni lede
48. Ewo ni awon elesin atohunrinwa ki i fe ki a lo fun won? (a) Ijala (b) Rara (d) Ege (e) Oriki-orile
49. Ta ni ki i se onkowe ere-onitan apileko ninu awon eniyan wonyi? (a) Akinwumi Isola (b) Oladejo Okediji (d) Oyebamiji
Mustapha (e) Afolabi Olabimtan
50. Ta ni osere ere-onise amerin-in-wa ninu awon osere wonyi? (a) Oyin Adejobi (b) Alabi Ogundepo (d) Toyosi
Arigbabuwo (e) Moses Olaiya
ASA YORUBA

1. Owe je ijinle __________ ti ki i tase ni gbogbo igba. (a) asa (b) ede (d) iwa (e) ikilo
2. Opele je irin-ise awon __________. (a) onisegun (b) babalawo (d) olosanyin (e) adahunse
3. Ki ni a fi n ki owu awo ti a n hun wo? (a) Okuuku (b) Ofi (d) Keke (e) Apasa
4. Ila kiko ni ise __________. (a) olona (b) oloola (d) ode (e) onilu
5. Tonbolo ni egungun __________. (a) omode (b) agunbaniro (d) agba (e) arugbo
6. Iro __________ lo n lo jagun laye atijo. (a) majesin (b) omode (d) agunbaniro (e) igiripa
7. Ki ni pakoko? (a) Agba oro (b) Omode oro (d) Orokoro (e) Baba oro
8. Imura obinrin ko ti i pe lai ___________. (a) ro aso (b) bo bata (d) we gele (e) kun oju
9. Agbere okunrin lo n __________. (a) wo ewu (b) bo bata (d) san tobi (e) kun osun
10. Iran Oba ___________ lo n ko ila eyo. (a) Alaafin (b) Owu (d) Alake (e) Aresa
11. Awon ilu wo lo n ko ila omo? (a) Ijesa (b) Oyo (d) Ekiti (e) Ife (e) Ondo
12. Ki ni a n polowo bayii: ‘gbeetu o, omi akerese’ (a) Isu (b) Agbado (d) Eja (e) Eran
13. Ori ________ ni a n le oja si. (a) pako (b) eni (d) ewe (e) ate
14. Ninu ere idaraya wo ni a ti maa n da ara? (a) Eke (b) Ayo (d) Okoto (e) Bojuboju
15. Ninu ere idaraya wo ni a ti le ba ijapa pade? (a) Itan (b) Okoto (d) Eke (e) Arin
16. Ki lo le mu eniyan lo yawo laye atijo? (a) Aso rira (b) Ile kiko (d) Oku sisin (e) Ounje jije
17. Ki ni a n pe eni to lo ya owo lodo elomiran? (a) Ajigbese (b) Ole (d) Olowo (e) Onigbowo
18. Ki ni oruko miiran fun onigbowo? (a) Ajigbese (b) Onigbese (d) Ologo (e) Abanikowo
19. Nibo ni a n sin oku agbalagba si ni ile Yoruba? (a) Ita (b) Ite (d) Odede (e) Igbo
20. Ki ni a n pe ogangan ibi ti a sin oku si? (a) Orori (b) Koto (d) Bara (e) Ponga
21. Awon wo ni a n pe ni ‘Olokiki oru’? (a) Oso (b) Aje (d) Iya (e) Baba
22. Iru eniyan wo ni a le pe ni oso? (a) Okunrin oloogun ika (b) Obinrin olojukokoro (d) Agba ilu (e) Arugbo kujokujo
23. Ona __________ ni awon aje n lo agbara won si julo. (a) rere (b) ibi (d) alaafia (e) igbadun
24. Awon wo lo n mu aje laye atijo? (a) Oso (b) Wolii (d) Alaadura (e) Atinga
25. Ki ni a n pe awon to n ran obinrin lowo lasiko ibimo? (a) Adahunse (b) Agbebi (d) Onisegun (e) Babalawo
26. ________ ati ________ lo po ju ninu ohun ti awon asawo-sesegun n lo. (a) Ogbon ati iro (b) Imo ati oye (d) Ebe ati
etutu (e) Awo ati oogun
27. ____________ ni oruko ile ipade awon ogboni. (a) Iledi (b) Itagbe (d) Igbale (e) Igboro
28. Awon ogboni ni agbara pupo ninu eto iselu ile ___________. (a) Ijesa (b) Ife (d) Egba (e) Ekiti
29. Oloye meloo lo n wa ninu awon Iwarefa? (a) meta (b) mefa (d) mewaa (e) mejo
30. ___________ ni olori oye obinrin ilu. (a) Iyalode (b) Iya abiye (d) Iyalaje (e) Iyaafin
31. Oye Bobagunwa je oye __________. (a) Ilu (b) ogun (d) ifidalola (e) esin
32. __________ ni oye re jemo eto oro-aje ilu. (a) Basorun (b) Balogun (d) Parakoyi (e) Oluwo
33. Ki ni ijiya oran ifipajale? (a) Iku (b) Ewon (d) Nina (e) Bibawi
34. Ki lo n fa oran dida? (a) Aigboran (b) Agidi (d) Aipa-ofin-mo (e) Igbo-mimu
35. Oruko miiran fun ile ewon ni ile _________. (a) tubu (b) isimi (d) ijiya (e) idande
36. Oja _________ ni a n pe ni Oja-Iba. (a) Oba (b) Baale (d) Basorun (e) Balogun
37. __________ ni olori ogun ile Yoruba. (a) Balogun (b) Aare-Ona-kakanfo (d) Seriki (e) Agbaakin
38. Ewo ni ki i se oruko amutorunwa ninu awon wonyi? (a) Ilori (b) Olugbodi (d) Dada (e) Aduke
39. __________ ni oruko ogun ti awon jagun-jagun lo ja ilu kan lati ko eru ati eru. (a) Sunmomi (b) Isagati (d) Ifinran (e)
Ilari
40. Ki ni aale ti a pa le nnkan je? (a) Ikilo (b) Ibawi (d) Eko (e) Itosona
41. _________ wa ni ara ohun to maa n da ogun sile. (a) Aala ile (b) Ajulo (d) Oro owo (e) Igberaga
42. ___________ lo ni ase ati gbogun ti ilu miiran ni ile Oyo. (a) Basorun (b) Balogun (d) Aare-Ona-kakanfo (e) Alaafin
43. Ise ogun jija ni ise iran ____________. (a) Ologbin-in (b) Abogunde (d) Onikoyi (e) Irese
44. Meloo ni awon oloye ogun ti a mo si Eso ni Oyo? (a) Aadorin (b) Aadojo (d) Aadota (e) Aadorun-un
45. Olori awon omo ogun to n fi esin jagun ni ___________. (a) Balogun (b) Sarumi (d) Bada (e) Seriki
46. __________ ni olori ogun ilu kan. (a) Balogun (b) Sarumi (d) Seriki (e) Asiwaju
47. A le ri ounje asemiro ninu __________. (a) eba (b) isu (d) epa (e) eso
48. Ewo ni a ki i fi sebe ninu awon wonyi? (a) Ororo (b) Epo pupa (d) Ori (e) Adi
49. Awon iserun eni ni _________. (a) obi eni (b) molebi (d) baba nla ati ebi eni (e) baba-nla ati iya-nla eni
50. Ewo ni a ki i fi i gunyan je ninu awon wonyi? (a) Esuru (b) Ewura (d) Igangan (e) Koko
ILO EDE

1. Odaran naa salaye lo bi ile bi eni ninu awijare re nile ejo. ‘Bi ile bi eni’ tumo si ____________. (a) kikun (b) repete (d)
ni soki (e) die
2. Edo oju ni Ladun fi wo Jide nigba ti won pade nidiiko laipe yii. ‘Edo Oju’ tumo si _____________. (a) oju kikoro (b) oju
sise (d) oju aanu (e) oju ife
3. Wiwon ti iyefun won ti mu ki buredi doko si opolopo ontaja nigba. ‘doko si nigba’ tumo si ___________. (a) buredi
doko ontaja (b) buredi kuta (d) buredi won (e) oja buredi y anile
4. O ye ki a gbaruku ti ijoba ki a baa le ni alaafia. ‘Gbaruku ti’ tumo si ___________. (a) gba eruku ti (b) tapa si ase (d)
dibo fun (e) se atileyin fun
5. Akekoo ti o se naa fi enu gbo ile daadaa ki oga ile-iwe to da a sile. ‘ Fi enu gbo ile’ tumo si __________. (a) toro
aforijin (b) fi enu re gbo ile (d) se alaye (e) jewo ese
6. Awon onifayawo naa baa won agbofinro mule nitori won ko fe ki enikeni gbeyin bebo je laarin won. ‘Gbeyin bebo je’
tumo si ___________. (a) tu asiri ikoko (b) se ofofo (d) ja afara (e) ja laarin ara eni
7. O hawo pupo; eleyii ko si fun un niyi rara. ‘Hawo’ tumo si __________. (a) ya ode (b) ni ahun (d) ya ole (e) ha owo
8. Won da a lebi nitori o le wa fin-in idi koko ju. ‘Wa fin-in idi koko’ tumo si __________. (a) topinpin (b) wa iwakuwaa
(d) saseju (e) fun ika mo
9. Oge ti ta le odomobinrin yen; ko si je ki o gboran si awon obi re lenu mo. ‘Oge ti ta le odomobinrin yen’ tumo si
__________. (a) odomobinrin yen se oge pupo (b) odomobinrin yen n se faari (d) odomobinrin yen n gberaga (e)
odomobinrin yen ti ta le oge
10. Olokiki oselu yen se agbako iku moto, o wa sinmi laasigbo aye. ‘Laasigbo’ tumo si __________. (a) igbadun (b) ibaje
(d) wahala (e) okiki
11. Bi a ba fi agbo fun eegun, ___________. (a) a si so o mole (b) a si dupe lowo alagbo (d) a si fi se saraa (e) a si jokun re
lowo
12. Bi ogiri ko ba lanu, ____________. (a) alangba ko le wo be (b) ile ko le wo (d) ogiri ko le di alapa (e) ogiri ko le wo
13. Pipe ni yoo pe, ___________. (a) omo ile-iwe yoo se oriire (b) wakati naa yoo de (d) talaka yoo dolowo (e) akololo
yoo pe baba
14. Osi ni i je ta-ni-mo-o-ri, ____________. (a) gbogbo aye ni i fe teru-tomo (b) ole ni i ja tile-toko (d) eko ni i seru domo
(e) owo ni i je mo-ba-o-tan
15. Agba ko si, ilu baje, baale-ile ku, __________. (a) iyaale-ile dara oko (b) ile dahoro (d) ile di taja-teran (e) omo di baba
16. Gbede bi ogun iya, ___________. (a) bi baba ba ku, ogun a dariwo (b) a-nini-lara-koko bi ogun baba (d) bi baba ba
ku, ile a dahoro (e) bi baba ba ku, omo a jogun re
17. Ki a fi ete sile, ___________. (a) ki a maa pa lapalapa (b) ki a maa wa oogun kiri (d) ki a so pe ara eni ya (e) ki a wa di
olokunrun kale
18. Araba tunra mu, ___________. (a) gbogbo igi lodo ti gbe lo (b) ki a sinmi agbaja (d) odo n gbe arere lo (e) ki a se ara
wa lokan
19. Maluu ti ko ni iru, ___________. (a) o ni iwo (b) Oluwa Oba ni i leesin fun un (d) Edumare ko ni je o ku (e) Olorun
Oba lo da a lola
20. Owo omode ko to pepe, _________. (a) ti gbogbo eniyan ko wo okun sokoto (b) tagbalagba ko wo akerengbe (d)
talakanle ni tosumare (e) tagbalagba ko de oke aja
21. Taye ran aburo re nise lati gba owo wa. O ri owo naa gba bo. Taye wa bi abure re leere pe ‘Eja n bakan?’ Idahun
aburo re ni ___________. (a) eja (b) akan (d) eye (e) eran
22. ‘Oba waja’ tumo sip e Oba ___________. (a) reju (b) ku (d) gun oke (e) wo aja
23. Itumo ‘fi enu ko’ ni __________. (a) soro daran (b) so isokuso (d) soro didun (e) salaye oro
24. Itumo ‘se amebo’ kiri ni ___________. (a) se iroyin (b) se alaye (d) se ofofo (e) se ofintoto
25. Jide ko nise, ko labo, afomo lo je fun awon ore re. ‘Afomo’ tumo si __________. (a) oluranlowo (b) iranse (d) afarahe
(e) akobata
26. ‘Asofofo ko gbegbaa, enu ope dudu lo mo’. A n lo owe yii fun ___________. (a) ibawi (b) imoran (d) awada (e)
imokanle
27. ‘Apepo leyin agba, agba n bow a kan o’. A n lo owe yii fun ___________. (a) awada (b) atunse (d) idajo (e) ikilo
28. ‘Da toro, da toro, da toro, agba ti ko da toro, omi obe ni yoo je’. Owe yii wa fun _________. (a) ikilo (b) awada (d)
imoran (e) imokanle
29. ‘Eni ti yoo joyin inu apata, ko ni wo enu aake’. Owe yii wa fun ___________. (a) awada (b) idajo (d) imoran (e) ibawi
30. ‘Ipako onipako la a ri, eni eleni ni i ba ni ri teni’. A n lo owe yii fun ___________. (a) ibawi (b) ikilo (d) idajo (e) isiri
31. ‘Obe ti bale-ile ki i je, iyale-ile ki i se e’. Owe yii wa fun _________. (a) imoran (b) ikilo (d) idajo (e) awada (e) isiri
32. Baba naa deru ba obinrin naa pe bi ko ba fe oun, ‘oun yoo gba oko re naa lowo re laipe ojo, oun yoo si so o di opo
osan gangan’. Eyi tumo si _________. (a) yoo gba oko re, yoo si gba obinrin naa pelu (b) yoo le oko re lo, obinrin naa
yoo si di alailoko (d) yoo e oko re, obinrin naa ko si ni ri oko re mo (e) yoo pa oko re, obinrin naa yoo si di alailoko
lairotele
33. Ewo ni ki i se owe tooto ninu awon wonyi? (a) Alufaa jona, e n beere irungbon (b) Ile oba to jo, ew lo bu kun un (d)
Ota n lulu ibaje, Oluwa oba o ni je ko dun (e) Adiye funfun, o dun-un je lobe
34. ‘E jowo, e siso loju eegun oro yii, ki a le mo ibi ti a n lo’. ‘Si aso loju eegun’ tumo si __________. (a) la oro mole (b) so
otito oro (d) pe oro so (e) se alaye oro
35. ‘Ise naa mu ni lomi ki o to pari’. ‘Mu lomi’ tumo si __________. (a) mu idera lowo (b) pe pupo (d) se ni wahala (e)
gba akoko pupo
36. ‘Bi ale ba le, a fi omo ayo fun ayo’. Owe yii ti inu asa _________ jeyo. (a) ere idaraya (b) iran-ara-eni-lowo (d)
igbeyawo (e) igbalejo
37. ‘Bi aare ba n se iwofa, won a ni olori buruku gbe ise re de, bi o ba somo olowo won a ni ko roju fi ata senu’. Owe yii
jeyo lati inu asa _________ (a) oge sise (b) ogun jije (d) owo yiya (e) ise owo
38. Obinrin so iwa nu ___________. (a) o kigbe iyaale (b) o loun o mori oko waye (d) o n book ja ninu ile (e) o ni ko si
ohun toko oun le se
39. Adeleke ko besu-begba to fi la oru koja. ‘Ko besu-ko begba’ tumo si (a) ko be esu (b) ko be egba (d) ko bikita (e) ko fi
ese ko
40. ‘Alani ko mo pe mo n gbe oun gesin aayan ni nigba ti mo so fun un wi pe oga ti dari jin in’. ‘Gbe oun gesin aayan’
tumo si (a) deruba oun (b) tan oun je (d) gbe oun ga (e) se aanu oun
41. ‘Bi o ba fo awo mama, o oo ri pupa oju won’. ‘Ri pupa oju’ ja si (a) aanu (b) iranwo (d) ibosi (e) ibinu
42. ‘Fotun we ose, fosi we otun ni owo fi n mo’. Owe yii jeyo lati inu asa ___________. (a) iwa omoluabi (b) iranra-eni-
lowo (d) ere idaraya (e) eko ile
43. ‘Bi iyan ewu ko yo ni, gelete re to ba ni leru’. Owe yii wa fun (a) awada (b) idajo (d) ibawi (e) ikilo
44. ‘Ejo awijare omo naa so ogbon ko, o si so were ko’. ‘So ogbon ko, so were ko’ tumo si __________. (a) doju tu (b) so
ologbon ati were ko (d) soro pupo (e) gba suuru
45. ‘Wa Ofintoto’ tumo si ki eniyan ____________. (a) se alaye oro yekeyeke (b) topinpin oro koja ibi ti o ye (d) kuna lati
so otito oro (e) moomo wadi oro (e) jiroro lori koko oro
46. ‘Gun igi rekoja ewe tumo si ki eniyan se __________. (a) aseyori (b) nnkan daadaa (d) isekuse (e) aseju
47. ‘Se kisa’ tumo si ki eniyan se ohun __________. (a) repete (b) arifin (d) iyalenu (e) aponle
48. ‘Sun kangiri’ tumo si _________. (a) ki eniyan ma le mi mo (b) sun kan ara ogiri (d) ki aare mu eniyan (e) ki agbara
eniyan pin
49. ‘Ti owo meweewa bonu’ tumo si ki a maa _________. (a) fi ika owo meweewa wa jeun (b) je ije apa laise aniyan fun
ojo ola (d) fi owo otun ati osi jeun leekan naa (e) fi owo jeun lailo sibi, fooku tabi obe
50. ‘Oko oba, ada oba’ tumo si ________. (a) oko ati ada oba (b) ase ijoba (d) dukia ijoba (e) ofin ijoba

You might also like