Professional Documents
Culture Documents
1 Odu Eji Ogbe
1 Odu Eji Ogbe
1 Odu Eji Ogbe
Òtóótó
Òróóró
Òtòòtò làá jèpà
Òtòòtò làá jèmumu
Lótò lótó ni wóón folú esunsuun sénu
Ohun torí ni torí
Ohun tòòri ni tòòri
Ohun torí tòòri làá rò fÒba Mòkín ní òde Ìrànjé
Kí Onirànjé ó lè baà fòtòtò èèyàn tani lórẹ
Béèrún bá jà tó bá tà
Wón a fòwó lówòó
Wón a fi giyàn balè
A dífá fún Ògo tééré
Èyi ti ń gbóguún lợ ilú gbèňdù gbẹndu èyin ợwợnràn
Wón ni kí Ògo tééré ó rúbợ
Ògo tééré si gbó ẹbợ
Ó rú
Ó gbó èèrù
Ó tu
Lódò okùnrin ni Ògo tééré wá
Ìlú gbèňdù gbẹndu ń bẹ lódò
Èyi obinrin kan
Ìlú kan ni
Wón ni kí Ògo tééré ó lòó jagun nílùú gbèňdù gbẹndu
Ó jagun jagun
Ó fokùnrin sèmú
Ó jagun jagun
Ó obinrin sèmú
Ó lòó mú ará ilú àìheyín wáyé
Kó móo lòó di ìgbèkùn
Ìgbèkùn táa bá di yíí
Ợmợ láá mùú bó ńbè
Ìgbèkùn òhún náà lá ń di lódò obìnrin
Tée dòní
Olódùmarè yóó fi obìnrin rere ké ẹnìkòòkan wa
Yó si fì ợmợ rere ké wa pèlú
Àwợn ń şe béè
Ó dáa fún wợn
N ní wón wá ń jó
Ní wón wá ń yò
Wón ń yin àwợn babaláwo
Àwợn babaláwo ń yin Ifá
Wón ni béè làwợn babaláwo tàwón wi
Òtóótó
Òróóró
Òtòòtò làá jèpà
Òtòòtò làá jèmumu
Lótò lótó ni wóón folú esunsuun sénu
Ohun torí ni torí
Ohun tòòri ni tòòri
Ohun torí tòòri làá rò fÒba Mòkín ní òde Ìrànjé
Kí Onirànjé ó lè baà fòtòtò èèyàn tani lórẹ
Béèrún bá jà tó bá tà
Wón a fòwó lówòó
Wón a fi giyàn balè
A dífá fún Ògo tééré
Èyi ti ń gbóguún lợ ilú gbèňdù gbẹndu èyin ợwợnràn
Yóó jà jàà jà
Yóó fợmợkùnrin sèmú
Yóó jà jàà jà
Yóó fợmợbìnrin sèmú
Yóó mùú ará ìlú àìheyín wáyé
Ìgbèkùn táa bá di
Ợmợ ní a rí níbẹ
Ìgbèkùn táa bá di.
Òtóótó
Òróóró
Separadamente, um tem que comer amendoim
Separadamente, um tem que comer cerejas
Em alimentos diferentes, se debe colocar Olú Esunsun na boca
As entidades de Orírí, pertencem a Orírí
As entidades de Orírí, pertencem a Orírí
Os atos de Orírí e Orírí, devem ser relatados ao Rei Mokín da
cidade de Ìránjè
Esse Onìránjè deu um agrado a alguém, uma pessoa muito
especial
Quando os soldados formiga fecharam o cerco e lhe picaram
Eles entraram com seu Exército e nos arrasaram completamente
E levaram terror aos seus prisioneiros
Lançaram Ifá para Ogo tèèrè, que perguntou sobre quem traria a
guerra para a cidade de gbèňdù gbẹndu èyin ợwợnràn
Lhe pediram para sacrificar
Ele escutou e fez o sacrificio, e também ouviu sobre a libre
pilhagem
E permitiu que isso acontecesse
Ògo tééré é homem,
A cidade de gbèndú gbèndú é a mulher. A parte de tras de uma
mulher.
É um outro tipo de cidade
Eles disseram a Ògo tèèrè “ Vá e instale a guerra na cidade de
Gbèndú Gbèndú”
Ele devia instalar uma guerra implacável
E tomar como prisioneiros os homens e as mulheres
E devolver à terra esses “Homens sem dentes”
E também tomar as coisas que até hoje tornam fortes nossos
filhos
As mesmas coisas que fazem crescer homens dentro das mulheres
E assim Olodúmàré deu a cada um homem e mulher, filhos
Eles continuaram vivendo para esse fim e a vida lhes foi muito
boa
Eles dançavam e regozijavam seus Babalawos
Seus Babalawos regozijavam a Ifà
Òtóótó
Òróóró
Separadamente, alguém tem que comer amendoim
Separadamente, alguém tem que comer as cerejas
Em alimentos diferentes, se debe colocar Olú Esunsun na boca
As entidades de Orírí, pertencem a Orírí
As entidades de Orírí, pertencem a Orírí
Os atos de Orírí e Orírí, devem ser relatados ao Rei Mokín da
cidade de Ìránjè
Esse Onìránjè deu um agrado a alguém, uma pessoa muito
especial
Quando os soldados formiga fecharam o cerco e lhe picaram
Eles entariam com um Exército que nos arrasaría por completo
Levando terror aos seus prisioneiros
Lançaram Ifá para Ogo tèèrè, que perguntou sobre quem traria a
guerra para a cidade de gbèňdù gbẹndu èyin ợwợnràn
Ele veio para o combate e capturou mulheres e homens
Os artefatos formados por nós, por favor, se convertam em filhos.
Olóòótó ti ń bẹ layé
Wón ò pógún mó
Sìkàsìkà ti ń bẹ níbè
Wón pò
Wón si ju ẹgbàábèje lợ
A dífá fún Òrúnmìlà
Nijó òrò gbogbo ó mó dùn ún nínú
Ifá pé òótó ni ká móợ sợ
Irúnmợlè ò níí jé á sợ òótó nu o
Wón ni ki wón ó móợ rúbợ ki Olóòótó ó pò
Wón ba rúbợ
Olóòótó bèrè síí wà láyé
Ayé ba ń gún
Wón ní Olóòótó ti ń bẹ layé
Wón ò pógún mó
Sìkàsìkà ti ń bẹ níbè
Wón pó
Wón si ju ẹgbàábèje lợ
A dífá fún Òrúnmìlà
Nijó òrò gbogbo ó mó dùn ún nínú
Ire ajé ni bá ń dùn wá
Kó móợ dun ipíin wa
Ká rájé rere ni
Òrò tí bá ń dunni
Kó jé àrankàn ẹni
Ire aya ni bá ń dùn wá
Kó móợ dun ipíin wa
Ká ráya rere fẹ
Òrò tí bá ń dunni làrankàn ẹni
Ire ợmợ ni bá ń dùn wá
Kó móợ dun ipíin wa
Ká rómợ rere bí
Òrò tí bá ń dunni làrankàn ẹni
Ire ilé ni bá ń dùn wá
Kó móợ dun ipíin wa
Ká rílé rere kợ
Òrò tí bá ń dunni làrankàn ẹni
Gbogbo ire ti bá ń dùn wá nílé ayé
Kó móợ dun ipíin wa
Ká rí rere gbámú
Gbogbo Òrò tí bá ń dunni
N làrankàn ẹni
Tradução:
A honestidade na terra é menor do que 20
Os desonestos na terra são mais do que 140.000
Lançaram Ifá para Orunmila
Quando se entristecia por todos, devido a sucessão de insucessos
e as atitudes humanas malígnas
Os Deuses não permitirão que se falte com a verdade
A eles foi dito que se sacrificasse sempre para que sempre
descobrisse os homens honestos sobre a terra
Ele sacrificou e pouco tempo depois os homens honestos
começaram a aparecer sobre a terra
Assim a vida se tornou algo bastante equilibrado
Eles disseram que a honestidade na terra é em número menor do
que vinte
Os desonestos e maldosos são em número muito maior do que
cento e quarenta mil
Lançaram Ifá para Orunmila
Quando se entristecía por todos, debido a sucessão de insucessos
e as atitudes humanas malígnas
É a necessidade de riquezas que nos entristece
Deixa-nos lamentar o nosso destino, porque qualquer pode ter boa
sorte, mas sempre tem algo pelo qual se entristece
Boa sorte com mulheres que me entristece
Deixa-nos lamentar o nosso destino, porque qualquer pode ter boa
sorte, mas sempre tem algo pelo qual se entristece
É a falta de bons filhos que nos entristece
Deixa-nos lamentar o nosso destino, porque qualquer pode ter
boa sorte, mas sempre tem algo pelo qual se entristece
É a falta de sorte para ter uma casa própria que nos entristece
Deixa-nos lamentar o nosso destino, porque qualquer pode ter boa
sorte, mas sempre tem algo pelo qual se entristece
É a falta de boas bençãos que nos entristece
Deixa-nos lamentar o nosso destino, pois sempre teremos aque
lutar pelas coisas boas em nosso destino
Ogbèyèkú
Ifà disse que as coisas maravilhosas que essa pessoa tem realizado
ou construído, não serão destruídas, e serão provas de éxito no
pasado e no futuro.
Ogbè Ìwòrì
O cliente está pensando em começar ou terminar uma relação. A
pessoa debe manter um bom relacionamento com seua amigos,
pois seria uma maneira de perder a confiança deles. Não se debe
contar os planos futuros a ninguém, pois sempre haverá inimigos
cercando a pessoa, mas não se debe ficar com raiva se alguém
descubrir.
Ogbè wèyin wò
Bájáà re o baà pa ikun
Awo Ợdẹ ló dífá fún Ợdẹ
Ợdẹ ni ń regbó méje èlùjù méje
Wón ní ki Ợdẹ ó sá káalè
Ệbợ ní ó şé kó tóó mợợ lợ
Ợdẹ gbébợ ńbè ó rúbợ
Ogbè wèyin wò
Bájáà re o baà pa ikun
A dífá fún Ònyagbè
Èyí to ń lợ rèé ba wợn múlè oko àiròdùn
Wón ní ó sá káalè Ệbợ ní ó şé kó tóó lợ
Ònyagbè gbébợ ńbè ó rúbợ
Wón lòó ba wón múlè légàn
Ợdẹ ń sợdẹ
Àgbè ń sàgbè
Wón wáá gbébợ ńbè wón rúbợ
Rírú Ệbợ èèrù àtùkèşù
Ệ wáá bá níní jèbútú ire
Jèbútú ire làá bá ni lésè ợba òrìşà
Ệ jé á móde mágbè kó lê yẹni
Àgbè ń tokoó bò
Ó mu Ìkókóró fún Ợdẹ
Ợdẹ ń tíjùú bò
Ó mu Ìkókóró ẹran
O si fún Àgbè
Ệ sàá jé á móde mágbè kó lê yẹni
Rírú Ệbợ èèrù àtùkèşù
Ayé wáá yẹ tùtúru!
Ogbe olhou para tras,
Para ver se seu cão tinha matado o rato Ikún
O adivinho do caçador, lançou adivinhação para o caçador
Que ia em direção a sete renomados arbustos na floresta
Foi dito que tivesse cuidado com esses lugarese que devia
oferendar antes da partida
Ele escutou e fez o sacrificio prescrito
Para ver se seu cão havia matado o rato Ikún
Adivinhação feita para o agricultor que ía escolher uma nova terra
para cultivar. Foi lhe dito para cuidar desses lugares e sacrificar
antes de ir. Ele assim o fez.
Ogbè Ìròsùn
Somente uma atitude espiritual pode restaurar o equilibrio. A
fortuna vem do extrangeiro, mas ele debe sacrificar a Odù com
muitos caracóis e ovos de galinha. A pessoa debe comportar-se
dentro dos principios de Ifá. Ifà vê uma mulher estéril que debe
fazer oferenda de 16 ovos para ter filhos.
Òkan pó!
Babaláwo Agogo lo dífá fún Agogo
Eyì gbòngàn gbòngàn
Babaláwo Àjìjà lo dífá fún Àjìjà
Mo ru wẹẹrẹ
Ó dà wẹẹrẹ
A dífá fún Òsìn Gàgààgà
Eyì ti ó kómo dà sì àtàrí
Wón ní kó rúbợ kó le baà bimợ
Òsìn Gàgààgà ngbébo ńbè
Ó rúbợ
Mo ru wẹẹrẹ
Ó dà wẹẹrẹ
Òsìn Gàgààgà ló bímợ báwònyì?
Mo ru wẹẹrẹ
Ó dà wẹẹrẹ
Òkan pó!
Adivinho de sino Agogô, adivinhou Ifá para o sino Agogô
Adivinho do sino Àjìjà, adivinhou para o sino Àjìjà
Eu sacrifiquei em quantidades
E dei mostras dessa quantidades
É Òsìn Gàgààgà que tem uma grande quantidade de filhos?
Eu sacrifiquei em quantidades
E dei mostras desse quantidades
Ogbè húnlé
Ilé ẹni làá hún
Ònà ẹni làá tò
Ònà tàà tợ rí níí şeni sìbálá sìbolo
A dífá fún Şeşeeşe kò lórí yìn
Èyì tíí sợmợ bíbí inú Àgbợnnìrègún
Gbogbo nnkan lòún ń şe ti wón ò yìn òún
Wón wá le yìn òún báyìí?
Wón ní ợpợlợpợ ẹyin ni kó tójú
Kí wón ó wáá sè é
Kó kó àwón Awo jợ
Kó şe oúnjẹ
Bí ón bá tí ń jẹun kí wón ó móợ mú ẹyin òhún jẹ
Ó bá rúbợ
Layé bá ń yin ní
Nnkan è dára
Kó bàjé mợ
N ní wá ń jó ní wá ń yò
Ní ń yin àwón babaláwo
Àwón babaláwo ń yin Ifá
Ó ní bèé làwón babaláwo tòún wí
Ogbè húnlé
Ilé ẹni làá hún
Ònà ẹni làá tò
Ònà tàà tợ rí níí şeni sìbálá sìbolo
A dífá fún Şeşeeşe kò lórí yìn
Èyì tíí sợmợ bíbí inú Àgbợnnìrègún
N ó lòórí ẹyin Ajé
Igba lewé eréyìn
N ó lòórí ẹyin Aya
Igba lewé eréyìn
N ó mợmợ lòórí ẹyin ni tèmi ò
Igba lewé eréyìn
N ó lòórí ẹyin Ợmợ
Igba lewé eréyìn
N ó mợmợ lòórí ẹyin ni tèmi ò
Igba lewé eréyìn
N ó lòórí ẹyin ire gbogbo nilé ayé
Igba lewé eréyìn
N ó mợmợ lòórí ẹyin ni tèmi ò
Igba lewé eréyìn
Ogbè Òbàrà
A pessoa precisa ter paciência e paz mental, cuidar bem de sua
esposa, porque as coisas boas virão através dela, não ser
miserável com ela e debe sacrificar um garrote ou estaca de
madeira. Existe um amigo (de baixa estatura) muito íntimo com o
qual se debe ter cuidado, para que críticas não lhe desviem do
bom camino. Terá um filho que lhe ajudará a pasar pelos
inimigos.
Òfòkisi Òfòkisi
A dífá fún Àfòn
Èyí tìí sòré Ìtí
Òré ní Àfòn òún Ìtí
Ìtí ò si ga tó Àfòn
Wón ń báyéé lợ
Ìtí bá ni ó ku bí Àfòn ó ti gbé gíga ẹ lợ
Ní ń bá ló mó Àfòn
Ní ń ló mó bíì kó pa á
Èşù ní ìwo Àfòn
Şe bóo rúbợ?
Àfòn lòún rúbợ!
Èşù ní: “Si jàn án ní gbóńgbó ò”
Nígbà ti Ìtí bá si ló lóó ló
Ợmợ Àfòn a si gbé e
A nà á mólè
Ợmợ Àfòn bá bá ìyá şégun Ìtí
Ìtí ò bá le bá Àfòn mó
N ní wá ń jó ní wá ń yò
Ní ń yin àwón babaláwo
Àwón babaláwo ń yin Ifá
Ó ní bèé làwón babaláwo tòún wí
Òfòkisi Òfòkisi
A dífá fún Àfòn
Èyí tìí sòré Ìtí
Ệbợ n wón ní ó şe
Àfòn gbébợ ńbè
Ó rúbợ
Ìtí kan ó mòmò lórí à á gbàfòón si
Àfòn ní ń bẹ léyìn to şẹgun gbogboo wón
Òfòkisi Òfòkisi
Lançou Ifá para Àfòn, a amiga de Ìtì
Elas sempre foram amigas, mas Ìtì era mais baixa do que Àfòn
Até que um dia Ìtí mostrou sua verdadeira face para Àfon,
Ela começou a retorcer-se diante de Àfòn, tentando apertar-la a té
matar, até que Esù disse: “Você sacrificou Àfòn?”, ela responseu
já agonizando “Eu sim”
Então o que está esperando para acertar ela com seu pau?, disse
Esù
Quando Ìtì estava enrolada em torno de Àfòn, os filhos dela
esticaram as mãos e atiraram Ìtì ao chão, facilitando para que
Àfòn a acertasse
Ìtì nunca mais intentou contra Àfòn
Ela e seus filhos louvaram ao seu Babalawo, e ele louvou Ifà
Òfòkisi Òfòkisi
Lançou ìfá para Àfòn, a amiga de Ìtí
Foi lhe dito para oferendar e elas escutou e fez
Nenhum fio chamado Ìtì terá Orí para suportar o garrote de Àfòn
Àfòn vem de sorrateiro para vencer com seus filhos
Ogbè Òkànràn
A pessoa pode fazer algo inesperado e que pode ter alcance
mundial. Há uma mulher que terá um filho que será coroado
como chefe e líder de uma importante familia. Se debe oferendar
para receber bençãos e riquezas que não se espera. Tem uma
mulher clara que deve oferendar para não perder sua boa sorte.
A ro gbódo léfòó
Èrò wèsì ni tebòlò
Ara ò níí ni ni kákááká
Kó níí ni ni kukuunkun
Ká mó leè dá kàkà dífá ẹni
A dífá fún Àyìnnipinpin
Tíí sawo ilé Ệlẹgùdumòró tán
Tí ón jẹ
Tí ón mu tán
Ệlẹgùdumòró bá ń lájé
Ó ń bímợ
Bó bá tún dé ńjợ miiin
A tún ni lágàńgà ợti ńkó?
Gbogbo ire ti Ệlẹgùdumòró ń wá
Gbogbo è ló rí
Ńgbà ó dijó kan
Ệlẹgùdumòró bá ní: “Gbogbo igbà n leléyìí ó móoó
bèèree ợti ní”
Yóó şe á móợ bèèree ợti ń gbogbo igbà
Ệlẹgùdumòró bá lòó ké si àwón “Igiri Ệgbárá igi”
Ó ní kí wón ó móợ bá òún şe nnkan òun
Wón ń şe é fun un
Kò rójútùú è
Ó tún lợòdò àwón Igiri Ệgbárá igi
Ệ wáá bóun şe nnkan òun
Wón tún şe é
Kò dáa
Ó tún lợòdò àwón À jó fórí sòpó òdèdè
Wón tún ń şe é
Kó wúlò
Wón ní Àyìnnipinpin rẹ ti ń ba ợ şe é ńjó kìínní ńkó?
Ó ní Lágàńgà ợti níí móoó bèèree!
Wón ní bó ba bèèrè Lágàńgà ợti ńkó
Ńgbà ti Àyìnnipinpin ń bèèree Lágàńgà ợti
Gbogbo nnkan tí àwón ń bèèree
Àwón ń ri i
Àwón táwòón lòó pé yí
Wón ón bèèree nnkankan lówó àwón
Şùgbón gbogbo nnkan ti àwón ń wá
Àwón ò ri
Ló ba tún ké si Àyìnnipinpin
Bó ti tún dé
Lágàńgà ợti ló tún bèèree
Ợti dá?
Ệ gbợti wá
Wón bá tún gbợti kalè
Àyìnnipinpin tún şe Ifá fún Ệlẹgùdumòró
Ilé è tún kún
Òún náà
Àşé òún ti sợnù lợ ni?
Ayé wáá yẹ Ệlẹgùdumòró
Ló wáá fa Àyìnnipinpin móra è
N ní wá ń jó ní wá ń yò
Ní ń yin àwón babaláwo
Àwón babaláwo ń yin Ifá
Ó ní bèé làwón babaláwo tòún wí
A ro gbódo léfòó
Èrò wèsì ni tebòlò
Ara ò níí ni ni kákááká
Kó níí ni ni kukuunkun
Ká mó leè dá kàkà dífá ẹni
A dífá fún Àyìnnipinpin
Tíí sawo ilé Ệlẹgùdumòró
Èyí ti ó bèèree lágàńgà ợti
Àwón “Igiri Ệgbárá igi”
Òtò lẹni wón ń wo Ifáa wóón fún
Àwón “Igiri Ệgbárá igi”
Òtò lẹni wón ń wo Ifáa wóón fún
Àwón À-jó-fórí-sòpó-òdèdè
Òtò lẹni wón ń wo Ifáa wóón fún
Àyìnnipinpin níí sawo ilé Ệlẹgùdumòró
Ệ jé n bÓgbèyónú mumi
Ệrú ń mu
Ợsin ń mu
Àyìnnipinpin
Ệ jé n bÓgbèyónú mumi
Àyìnnipinpin
A ro gbódo léfòó
Èrò wèsì ni tebòlò
Aquele que não se sente doente
Mas mesmo assim está cabisbaixo
E não é capaz de curvar-se para lançar adivinhação
Adivnhou para Àyìnnipinpin, o sacerdote da casa de
Ệlẹgùdumòró
E ao chegar a casa de Ệlẹgùdumòró, pediu uma grande garrafa de
vinho
Ệlẹgùdumòró brindou, depois que lhe foi preparado sua receita de
Ifá
Eles comeram e beberam juntos
Ele começou a ter riquezas, filhos e boa-sorte, e sempre brindava
seus Babalawos com uma garrafa de vinho
Mas um dia ele se perguntou, “Porque dar garrafas de vinho ao
seu Awo?”
E então ele foi chamar o sacerdote “Igiri Ệgbárá igi”
Mas isso não fez bem para sua vida, e ele entáo procurou outros
como À-jó-fórí-sòpó-òdèdè, mas também não foi bom e as
pessoas então perguntavam onde estaba o Babalawo que lhe deu
tanto sucesso
“Ele sempre pediu grabdes garrafas de vinho pelas coisas que eu
pedia a Ifá”
“É melhor que peça grandes garrafas de vinho e que resolva as
coisas, do que pedir coisas mais baratas e não resolver nada”
Ệlẹgùdumòró voltou a chamar Àyìnnipinpin
E quando chegou, logo pediu uma grande garrafa de vinho, que
chegou junto com miutas outras
De novo na casa de Ệlẹgùdumòró havia bençãos de dinheiro,
filhos boa-sorte, etc…
Sim, eu danço e elogio meu Babalawo e ele elogia a Ifá
A ro gbódo léfòó
Èrò wèsì ni tebòlò
Aquele que não se sente doente
Mas mesmo assim está cabisbaixo
E não é capaz de curvar-se para lançar adivinhação
Adivnhou para Àyìnnipinpin, o sacerdote da casa de
Ệlẹgùdumòró
E ao chegar a casa de Ệlẹgùdumòró, pediu uma grande garrafa de
vinho
Os sacerdotes Igiri Ệgbárá igi e À-jó-fórí-sòpó-òdèdè,
adivinharão Ifá para outras pessoas
O sacerdote da casa de Ệlẹgùdumòró é e será Àyìnnipinpin
Deixa-me beber agua com Ogbèyónú
Os escravos e servos bebem
Deixa-me beber agua com Ogbèyónú
Àyìnnipinpin
Ogbè Òsa
Ifá pede a essa pessoa para sacrificar para que sempre encontré a
boa-sorte e a fortuna. Ifá disse que as coisas boas passam ao seu
redor, passam pelo seu lado, sem chegar a lhe tocar. Deve´se
pferecer a pele de uma hiena. Aconselham que sacrifique bastante
a Ifá, tal que tenha algo para mostrar. Ifá diz que essa pessoa não
deve der detido ou preso, para que isso não aconteça deve se
preparar Èkuru, polvilhar com Iyerosun já rezado e enterrar na
terra.
Ogbè ká relé
Ợmợ Ợsìn
Ogbè ká relé
Ợmợ Ợrà
Ogbè ká relé
Ợmợ Ògún lè lèè lè alèdé
A dífá fún Ìtipónợlá aya Ahoro
Wón ní kó rúbợ
Agbà ó yá ó bá lóun ò saya Ahoro mợ
Wón nilé tò ti kúò
Mó yáa padà sibè
Ìtipónợlá ba rúbợ
O şe é
Níbi ó ti sa kúò
Mó ba padà sibè
Ahoró ni béè làwợn Babaláwo tòún wí
Ogbè ká relé
Ợmợ Ợsìn
Ogbè ká relé
Ợmợ Ợrà
Ogbè ká relé
Ợmợ Ògún lè lèè lè alèdé
A dífá fún Ìtipónợlá aya Ahoro
Ìtipónợlá o
Aya Ahoro
O ó tùún délé ợkợ àárò
O ó tợkợ àtijợ un fé!
Ogbè ká relé
Filho de Ợsìn
Ogbè ká relé
Filho de Ợrà
Ogbè ká relé
Filho de Ògún lè lèè lè alèdé
Lançaram Ifá para Ìtipónợlá esposa de Ahoro
A quem se lhe pediu para sacrificar
E isso aconteceu depois de ter se divorciado de Ahoro
A casa que você deixou…Terá que voltar!
Eles disseram
E ela considerou o sacrificio e assim o fez
Seja lá para onde você for, irá retornar
Ogbè ká relé
Filho de Ợsìn
Ogbè ká relé
Filho de Ợrà
Ogbè ká relé
Filho de Ògún lè lèè lè alèdé
Lançaram Ifá para Ìtipónợlá esposa de Ahoro
Eu te adverti Ìtipónợlá, que era esposa de Ahoro
Que voltaria e se firmaría com seu primeiro esposo
Ogbè ká re káà ká bò dé
A dífá fún Ìgbín
Ti ń lợ rèé gba káà lợwợ Alábahun
Ahun ló ni káà télè rì
Ìgbín bá gbà á lợwợ è
Ó mú káà lợ
Wón ní ó fíí lè
Wón ní ńgbà ó bá yá
“Yóó fíí káà sílè fún ợ”
Ahun bá mú káà míìn
Wón ń báyéé lợ
Ńgbà ó bá yá
Ti ợn bá mú Ìgbín
Wón ó bàá yợ Ìgbín kúò ńnú è
Wón ó ju kòròòfo è nù
Wón ò bá níí pè é ní káà Ìgbín mợ
Káà Ahun ni wón ó mợợ pè é
Ó bá di káà Ahun
“Wón ni ńgbà ó kú”
Ợ ò gba nnkaàn rẹ?
Ahun gba nnkàn è
Ogbè ká re káà ká bò dé
A dífá fún Ìgbín
Ti ń lợ rèé gba káà lợwợ Alábahun
Ìgbín wáá kú tán
Ahun gba káà lợwợợ wợn
Wón a ní káà Ahun níí şe!
Ogbè ká re káà ká bò dé
Adivinhção lançada para o Caracol
Inicialmente foi aTartaruga a proprietária da casca
Mas o Caracol à pegou e saiu com ela
Eles acoselharam a Tartaruga que deixasse a casca para o Caracol
Eles previram que depois de um tempo, ele deixaria a concha
A Tartaruga coseguiu outra casca para sí mesma
Depois de muito tempo, o homem separou a concha da carne,
descartando a concha e ficando com a carne
E até hoje não se fala “ a casca do Caracol” e sim a da Tartaruga
E assim foi como voltou o casco para a Tartaruga que disse, “
Quando ele morre?”
E eles disseram, “ Não recuraste o teu casco?”
Ogbè ká re káà ká bò dé
Adivinhção lançada para o Caracol
Que vinha para tomar a casa da Tartaruga
O Caracol então morreu
A Tartaruga recuperou seu casco
E eles disseram, “ Sempre pertenceu a Tartaruga”
Ogbè Òtúrúpòn
Ifá disse que a boa sorte viria para essa pessoa.
Deberá oferendar uma boa quantidade de dinheiro e a vida lhe
será boa.
Ifá disse que o bom nome implatado pelos seus ancestrais não
pode ser difamado. Está avisado para não desobedecer seus pais.
É acoselhado não desperdiçar a herança deixada pelos seus
antepassados, para que seus ancestrais não se lamentem no Céu.
Ogbè tợmợ pòn
Abiamợ súmmợ sí
Àgbàpòn ó lérè
Bợmợ bá ń sunkún
Ìyá làá kéé sí
A dífá fún Sèkèrè
Sèkèrè tíí sợmợ Àlákòlé
Òún leé lájé?
Òún le láya?
Òún bímợ?
Ayé oún dáa?
Wón ní kí Sèkèrè ó rúbợ
Wón ni ijó ní ó móợ jó
Ayò n layée rè
Wón ní ợpợlợpợ owó ni ó fi rúbợ
Sèkèrè rúbợ tán
Ajé dé
Kò ribi kó ó si mó
Ó bá sowó mó ara è
Wón ń pé Sèkèrè ló lówó tó báyìí?
N ní wá ń jó ní wá ń yò
Ní ń yìn àwợn Babaláwo
Àwợn Babaláwo ń yìn Ifá
Ó ní béè làwợn Babaláwo tòún wí
Ogbè tợmợ pòn
Abiamợ súmmợ sí
Àgbàpòn ó lérè
Bợmợ bá ń sunkún
Ìyá làá kéé sí
A dífá fún Sèkèrè èyí tíí sợmợ Àlákòlé
Sèkèrè araà rẹ lokùn
Sèkèrè araà rẹ lájé gbé ń so
Ajé wáá rí rẹrẹ báwònyí o
Sèkèrè araà rẹ lokùn
Sèkèrè araà rẹ lájé gbé ń so
Şeguí sóòrúpa
Òkèrè n kerenbètè
Ìyà àlà larugbòn ikú
A dífá fún Ợlợmợ a ji foókợ sára
Òún lê lóókợ to dáa láyé òun báyìí?
Bàbá òún tí lóókợ
Wón ní kó rúbợ
À á séé mợ Ợlợmợ a ji foókợ sara
Làá pé Ìrókò
Bí ợn bá ge Ìrókò tán
Tí ò si ńbè mợ
Wón ó túún móợ fibè júwe
Wón a pé ńdíí Ìrókò
Ifá pé ki eléyìun ó rúbợ
Ìrókò ba rúbợ
Ni ợn ba ń ki gbé è kárí ayé
Ayé yẹ Ìrókò
Şeguí sóòrúpa
Òkèrè n kerenbètè
Ìyà àlà larugbòn ikú
A dífá fún Ợlợmợ a ji foókợ sára
Ợlợmợ a ji foókợ sára nìrókòó jẹ
Ifá jé á jợ lóókợ rere ńlé ayé
Porongodo!
Şeguí sóòrúpa
Òkèrè n kerenbètè
È uma carga pesada para o portador do cesto da morte
Lançou adivinhação para Ợlợmợ a ji foókợ sára
Que se perguntava se teria um bom nome sobre a terra?
“Meu pai teve um nome distinto!”
Foi pedido para ele sacrificar
Como nos comparar a Ợlợmợ a ji foókợ sára?
Pois é aquele a quem chamamos de “Arvore de Ìrókò”
Mesmo sabendo que houve uma dessas árvores em determinado
lugar, e que não existe mais, se continuará dizendo:
“Ao lado da Àrvore de Ìrókó”
Ìrókò sacrificou
E eles proclamaram seu nome em todos os cantos como majestoso
e muito importante, assim como muito respeitoso e honrado.
E a vida foi muito boa para a Árvore de Ìrókò
E ele disse Şeguí sóòrúpa
Òkèrè n kerenbètè
É uma carga pesada para o portador do cesto a morte
Lançou adivinhação para Ợlợmợ a ji foókợ sára
Ợlợmợ a ji foókợ sára é o sobrenome da Árvore de Ìrókò
Por favor Ifá, deixe que nossos nomes sejam honrados e
respeitados sobre a terra
Porongodo!!!
Ogbè Òtúá
Ifá disse que coisas muito boas estão vindo ao encontro dessa
pessoa. Essa pessoa esta destinada a ter fortuna quase no final de
sua existencia, assunto que não debe entristece-lo, porque debe
fazer oferenda somente para uma vida longa.
Ifá pede para que essa pessoa seja tranquila e muito calma, que
debe sacrificar para Ệgbérun, assim como conviver e alimentar
crianças muito pequeñas.
Ogbè Ìrètè
Ifá se refere a tres pessoas que devem combinar esforços para
gerar riquezas e lucros. Ifá diz que eles nao são irmãos de sangue.
Se é comerciante, ele diz que é em outra cidade que ele fará sua
fortuna. Se é um trabalhador, seu trabalho lhe deixará rico. Ifá diz
que seus inimigos desejam que ele seja capturado pelos Ajogun,
mas isso não acontecerá. Ifá deseja que sacrifique.
Àkùkợ tó kợ lanàá
Ìkợ ire ló kợ
A dífá fún Erin
Erin ń sunkúun póun ò lólá
Ệbợ n wón ní ó şe
Àkùkợ tó kợ lanàá
Ìkợ ire ló kợ
A dífá fún Ệfợn
Ệfợn ń sunkúun òún ò níyì
Ệbợ n wón ní ó şe
Àkùkợ tó kợ lanàá
Ìkợ ire ló kợ
A dífá fún Eşinşin
Ń lợ rèé bá wón múlẹ oko àì ródún
Ệbợ n wón ní ó şe
Àwợn mètééta bá rúbợ
Erin rúbợ
Ệfợn náà rúbợ
Eeşin náà ò gbéyin
Àwợn mètééta bá là
Wón bá bèrè síí yin àwợn babaláwo
Wón ní Àkùkợ tó kợ lanàá
Ìkợ ire ló kợ
A dífá fún Erin
Erin ń sunkúun póun ò lólá
Ệbợ n wón ní ó şe
Erin rúbợ
Erin lola
Àkùkợ tó kợ lanàá
Ìkợ ire ló kợ
A dífá fún Ệfợn
Ệfợn ń sunkúun òún ò níyì
Ệbợ n wón ní ó şe
Kó le baà níyì
Ệfợn rúbợ
Ệfợợn níyì
Àkùkợ tó kợ lanàá
Ìkợ ire ló kợ
A dífá fún Eşinşin tíí sợmợ ìkéyìín wợn leńje-leńje
Wón ní ó rúbợ kó lè baà toko là wálé
Eeşin gbébợ ńbè
Ó rúbợ
Eeşin wáá toko là wá inú ilé
Erin lola o
Ệfợn níyì
Eeşin nikàn ló roko
Lòó lá o
Ifá póun pé ire fún eléyiun.
Ogun n wón ni ó pá a
Ilé ni ń moó kún ilé
Okè èèpè ni à sàì sun
Akànpò èwù ni ń kàn
Kó níí rénìkan à á báá şeré
Orí akợ ẹşin orí abo ẹşin ni wón tí ń bá a
A dífá fún ẹsẹ kan şoşo Ogbè
Ti ń lợ rèé bá Ìrètè şégun
Ayé yẹ wón
N ní wá ń jó ní wá ń yò
Ní ń yìn àwợn Babaláwo
Àwợn Babaláwo ń yìn Ifá
Ó ní béè làwợn Babaláwo tòún wí
Ogun n wón ni ó pá a
Ilé ni ń moó kún ilé
Okè èèpè ni à sàì sun
Akànpò èwù ni ń kàn
Kó níí rénìkan à á báá şeré
Orí akợ ẹşin orí abo ẹşin ni wón tí ń bá a
A dífá fún ẹsẹ kan şoşo Ogbè
Ti ń lợ rèé bá Ìrètè şégun
A şégun nígbà yí ò
A şégun
Ệsẹ kan şoşo Ogbè
Ó ti bá Ìrètè şégun láyé
Ogbè Òşé
Ifá diz que essa pessoa tem tentado muitas coisas na vida, mas
não tem obtido éxito. Para ter éxito, terá que oferecer o sacrificio
correspondente. Buscará uma vasilha para juntar a agua que se
acumula ao lado do altar de Esù.
A pessoa comprou algo que lhe troxe muita tristeza por muitos
motivos. Ifá diz que não se desespere, pois a longo prazo ele terá
riquezas e melhorias económicas e sociais.
À şé síhìín
À şé sóhùún
Lomi koto è é fíí kún
Tíí fíí wợnú ilé
A dífá fún Odídẹré
Tí ń foşù gbogbo şòwò èjè
Odídẹré ní ń şe nňkan ni ò lórí yin
Òun le şe nňkan rere báyìí?
Wón ní kí Odídẹré ó rúbợ
Wón ni gbogbo nňkan è ní ó bára mu
Odídẹré bá rúbợ
Ó nibợ tán layé bá jẹ é
Gbogbo nňkan tí ò ti dáa
Ti ò tí lájé
Ti ò ti bímợ
Oşù gbogbo ni fí ń şòwò èjè
Wón ni kó tójú nňkan ipợnmi
Ni kó fi rúbợ
Wón gbẹbợ fún Èşù
Béré béré ìdi è bá tún dowó
Ni ínú è ń dùn
N ní wá ń jó ní wá ń yò
Ní ń yìn àwợn Babaláwo
Àwợn Babaláwo ń yìn Ifá
Ó ní béè làwợn Babaláwo tòún wí
À şé síhìín
À şé sóhùún
Lomi koto è é fíí kún
Tíí fíí wợnú ilé
A dífá fún Odídẹré
Tí ń foşù gbogbo şòwò èjè
Yóó dợmợ
Òwò èjè kan òwò èjè kàn
Tàwa şe lóşu yìí
Yóó dợmợ
ợmợ ni ò mòmò dà