Professional Documents
Culture Documents
Ogbon Fun Sisi Akoso Awon Ihuwasi Igba Odo
Ogbon Fun Sisi Akoso Awon Ihuwasi Igba Odo
Oniwaasu 3:1-6, Orin 139:14, 15, III Johannu 2; Oniwaasu 10:8, II Kor. 10:12
Idaduro nkan osu (Menopoosi) kii se arun bikose isele adayeba ninu ago ara. O je akoko idaduro nkan
osu obirin. Menopoosi toka si opin akoko omo bibi fun obirin ti o wa laarin odun marun-din-laadota si
odun marun-din-logota (45-55) nigbati ise oje (ovarian) ba ti nkaare. O je eyi ti nsele die-die fun opo
odun ki o to dawo duro patapata. O tile lee dawo duro lojiji ninu awon miran laisi ikilo tabi fun won ni
amin kankan (o yato laarin enikan si enikeji). Menopoosi je ona ti Olorun fi n dekun omo bibi ti o lewu
fun ilera wa.
1. ITUMO ATI IFARAHAN MENOPOOSI
Menopoosi n waye lara opolopo obirin ti o wa laarin odun 45-55 ati lapapo odun mokan-le-
laadota (51). Nigba ti nnkan osu ko wa mo fun osu mejila, a o wipe Menopoosi ti bere. Iru ayipada ti o
de ba ara obirin bi eyi nwaye nigbati eyin re ko lee mu ohun ti o le mu nnkan osu wa mo. O seese fun
awon obirin lati ni iriri Menopoosi kiakia ni bi won ti npe ogoji odun (40 years) tabi ki o pe bi Ogota
odun (60). Bi obinrin ko ba wa rii lehin ogota odun, o ni lati lo sodo awon onisegun oyinbo fun ayewo.
Bi obirin ti ko i tii pe Ogoji odun ba wo Menopoosi, o je idawoduro nnkan osu laito akoko tabi nkan osu
mi sonu, mo ba ro pe o ti doyun. Eyi lee waye nipa tairoodu, atogbe- mellitosi, kimoterapi, redioterapi.
Idawoduro nkan osu laito asiko ni a fi idi re mule nipa ipele homoonu(hormone) ninu eje (FSH ati LH).
Awon Obirin ko gbodo se aniyan nipa Menopoosi, nitori o je isele abalaye niwon igbati won ti bi awon
omo ti won fe tan.
AWON IFARAHAN: Ami gboogi re ni obirin ti ko ri nnkan osun fun odun kan ti ko si fun omo lomu
tabi ni oyun. O toka si opin lati le bi omo. Bi awon obirin kan ti n wo Menopoosi laasi ami kankan,
beeni awon kan maa nri awon ami ati iriri wonyi:
Igbona rampe: Ooru ti njade lati inu wa si ori pelu ilaagun. Eyi n sele si obirin meta ninu merin (75-
85%).
Airi Orun sun: Eyi ni ibi keji si igbona rampe, ailera, efori, iyipokiri, imolara aare ara, a-i-le-fi okan si
nkan, riro lati subu je ara awon ami Menopoosi ti o nwaye nitori iyipada awon homoonu ninu ara,
Ara wiwuwo: Nitori omi ti n rogun ninu ara, ti o wopo ni isale ikun, obirin naa a ni imolara ti o ga,
ibinu ati irewesi fun ero ainireti ati aipe. A wa rii pe oun ti n di arugbo.
Awon irora ni ori ike: Ipele kasiomu ninu ara yoo dinku latari awon ayipada homoonu. Awon ami
miran ni pipadanu ife fun ibalopo, awe oju ara ti o gbe pelu yiyun, ara gbigbona, titeba ati asteoporosis ti
o fo, isoro ounje dida, gbigbagbe nnkan ati rire.
2. AWON ASITUNMO NIPA MENOPOOSI: Menopoosi ni igbese ninu ago ara ti kii se arun ti o ye
lati maa beru. O je iyipada awon homoonu ti o nmu awon ami nipa ti ara wa. Opo ni o gbagbo wipe opin
ni o de bayi, ti awon miran si nii lokan pe Menopoosi yoo mu opin de ba ebi ati ifarakanra won. Awon
kan ro wipe ngbati ko seese fun awon lati ni oyun mo, o je anfaani fun won lati maa se isekuse tabi ba
ara won je kiri. Awon obirin kan beru re, won si di oniye-rira. Yoo rii pe oun ti n darugbo beeni yoo wa
ma a se iyemeji agbara re. O se pataki fun awon obirin kristeni lati yago fun iberu ati ijewo ti o lodi. (II
Kor 5:17) wipe obirin kristeni ni eda tuntun.
Awon obirin oniwa-bi-Olorun ti jeri i gbigbadura saaju ibere Menopoosi ti won si ri idasi Olorun ni iru
akoko bi eyi laye won, ti ko si fun won ni irora pupo. Oluwa lee ran enikan ti o fi igbekele re patapata
sinu Re lowo.
3. SISE AKOSO AKOKO MENOPOOSI RE
Akoko Menopoosi ko tunmo si pe opin ni o ti de. O tunmo si pe idaji aye re ti koja lo. Opolopo
itoju ni o wa fun igbe-aye gbadun re.
i. Isakoso Isegun fun Menopoosi: Iru akoko yii ki n se igba ti obrin gbodo simi le oogun tabi da oogun
lo fun ara re. Awon oogun bii sedatifu, relaxants ati tranquilizer le je iranlowo fun awon obirin pelu isesi
ti o yipada. Lilo oogun ti o ni oestrogen lee se adinku ba nini oestroprosis, ida eegun, awe oju ara
gbigbe. Awon obirin miran maa n lo fun itoju aropo hoomonu lati le din irora awom ami menopoosi ku,
Ninu gbogbo awon itoju wonyi, awon obirin gbodo sora fun awon olutaja oogun ti kii se akose-mose
onisegun oyinbo. Oogun ti o lodi lee yori si arun jejere ni iru akoko bi eyi. Ayewo igba-de-igba se pataki
ni iru akoko bee.
ii. Isakoso ti ara fun Menopoosi: Eyi nii se pelu awon ohun ti a n je, ere idaraya, isimi ti o joju pelu
ibugbe ti o dara, jije efo ati eso pelu awon epa, opolopo omi, ewa soya, ounje olora ati amunukun die.
Opo ounje ti o ni eronja kasiomu (Calcium) ninu laarin ounje wa lojoojumo. Apapo Kasiomu ti a n je
lojoojumo ni lati to 1500mg lehin ti a ba ti pe omo odun marun-din-laadota (45 years). Jije awon ounje ti
o ni asiidi (acidic), ohun mimu didun mirin-mirin, oti, ora ati kaffeinated ni o gbodo dawo duro. Orisirisi
eja ati awon ounje ti o ni eronja daadaa ti o nse ara loore ni o dara pelu. Isimi ati sise ere idaraya ni a
nilo ni iru akoko yii, ibusun ti o le niwon iba, ati yara ti o ni afefe daradara pelu awon akiyesi alaabo ni o
boju mu. A gbodo duro ti ololufe wa nikan, ki a si maa jo gbadun ibalopo sugbon ki a yago fun ibalopo
pelu awon opolopo okunrin miran. Imototo ara eni naa se pataki pelu. A lee lo skimmed milk/cocoa dipo
“bournvita” ati miliki skimmed. Bee ni a le be awon akose-mose nipa ohun jije ati awon arakunrin tabi
awon adari wa ti o je eleto ilera wo.
iii. Isakoso ti Emi fun Menopoosi
(I Peter 5:7; Isaiah 46:4; 33:27, Jer. 29:11; II Cor. 5:7 )
A lee ran awon obirin lowo lati wo Menopoosi laisi ibeeru tabi aniyan sise. Oro Olorun gba wa
niyanju lati ko gbogbo aniyan wa le E, yoo si se itoju wa. O se ileri lati mu wa laa ja nipataki igba ogbo
wa. Gbekele Olorun, se asaro ninu oro Re, gba awon ileri Re mu, ki o si maa ni ijewo rere. Yera fun
aniyan sise. John 15:2-7. Maa so eso ninu ogba ajara Olorun, Oore-Ofe Re yoo tesewaju lati maa to fun
o (Amin).