Download as pdf or txt
Download as pdf or txt
You are on page 1of 6

MAT.

10:8 (INTERNATIONAL SECRETARIAT)


4, EBENEZER CHURCH ROAD, OLUWO JUNCTION, OFF ABIOLA WAY, ABEOKUTA

WBS 1268
TUESDAY 21ST NOVEMBER, 2023

EKO: IBAWI NINU IJO OLORUN


IBI KIKA: HEBERU 12: 5-8

Ninu ęko wa ti oni ni a o ti maa şe agbeyewo ohun pataki ti a npe ni ibawi ati iwulo rę ninu ljo
Olọrun. Gegębi ibi kika wa, Emi Olorun șipaya fun wa bi ibawi ti şe pataki to. Afi han wa pe bi
a ba wa laisi ibawi,a ję omọ-ale - Heberu 12:8.
Fun alaye ni ękunrẹrę a o wo ęko yi labę isori marun otooto
(a) Itumo ibawi ati ijo Olorun
(b) ldi Pataki ti ibawi fi wa ninu ljo Olorun
(d) Awon ti o yę lati bawi ninu ljọ Olọrun
(e) Ona abayọ fun awọn ti a bawi
(ę)Ojuşe rę si awon ti o wa labę ibawi
(A) ITUMO IBAWI ATI IJO OLORUN:- Ibawi ni iya ti a fi je eniyan nigbati o se ohun ti ko to.
Fun apeere: ljoba aye maa nso arufin si ewon nitori iwa odaran beeni awon obi si maa nba
awon omo won wi nigbakugba ti won ba se ohun ti ko dara Deuteronomi 8:5. ljo Olorun ni
apejopo awọn omo Qlorun ti a ti pe jade lati inu aye wa si odọ Jesu Kristi. Ise Aposteli 1:15.
(B)PATAKI BAWI NINU IJO QLQRUN :- Bi ibawi ti şe pataki ni orile ede, ilu, awujo tabi
ęlęgbęjęgbę, ile-ęko ati idile lati dękun iwa ibaję bęę gęgę ni o şe pataki ninu ijo Qlgrun. Idi
pataki ti ibawi şe wa ninu ijo Qlorun ni lati dena iwa ibaję ati lati şe afomo ijọ.
1Timotiu 5:20, Johanu 2:13-16.
(D) AWON TI O YĘ LATI BAWI NINU IJQ QLQRUN:- Orọ ibawi ko yo ęnikęni silę ninu ijo
Olorun bęrę lati odo olori titi de omo ęhin. Gbogbo eni ti o ba se si ofin Olorun ti o wa ninu lwe
mimo ati igbekale ijo ni a gbodo bawi laisi ojusaju. Gbogbo eni ti o ba nse awon ohun ti o lodi
bi:-Şişe agbere, mimu oti lile ati igbo, jijale, lilu eniyan ni jibiti, kiko owo ję, hihu iwa
alonilowogba. Şişe egbę okunkun, gbigba aya ęlomiran, tabi liloyun siwaju akoko igbeyawo,
tita awon oja ti ko tọ, jija ija ajaigbula ati şişe awon ohun miran ti a ko le darukọ tan şugbon ti o
le mu itiju ati ęgan ba ijo Qlorun tabi da ijo Olọrun ru.Gbogbo ęni ti o ba ni owo ninu awon
ohun ti a ti ka şaaju wonyi ni o ye fun ibawi.
Die ninu ibawi ti elese le gba niwonyi:
1.Gbigba ise ti eni bęe nse lowo re fun saa kan bi o ba ję oşişe ninu ijo
2. Fifi awon anfani biba iru eni bee se ayeye eyikeyi dun
3. Dida iru eni be lati ori pepe pada sinu ijo bi o ba je osise ti ndari isę ninu ijo.
4. Yiyo kuro ninu ijo (1 Korinti 7:10-11, 1 Korinti 5:11-13, Titu 3:10-11.)
(E) ONA ABAYỌ FUN AWỌN TI A N BAWI:- Gbogbo enikeni ti wọn se ti a si n ba wi gbodo fi
okan tutu gba iru ibawi be nitoripe a ba won wi lati gba emi won la ni ojo Jesu Oluwa ni
1 Korinti 5:3-5. Awon iru eniyan be gbodo mu ara won wa si abe iteriba pęlu emi
ironupiwada,ki won si tun wa aye lati wa oju Oluwa fun idariji ese won. O je ohun ti o buru loju
Olorun ki enikan maa sa lati ijo kan lo si ijo miran nitori ibawi. Owe 15:3.
(Ẹ) OJUŞE RẸ SI AWỌN TI O WA LABE IBAWI:- Ojuşe rę Pataki ni lati ba wọn sọro ti o le
mu wọn ronupiwada kuro ni aşişe won. Bakanna a ko ni lati ta won nu patapata. Galatia 6:1,
A ko gbọdo ri enikeni bi eni ti o nsoro lodi si idajọ ti a şe fun iru awon eniyan bee.
Lakotan owo ibawi ko se fa sehin ninu ijo Olorun, bee si ni gbogbo awon ti won ba si wa labe
ibawi kan tabi omiran ni won gbodo gbe emi ironupiwada tooto wo Heb 12:11.
MAT. 10:8 (INTERNATIONAL SECRETARIAT)
4, EBENEZER CHURCH ROAD, OLUWO JUNCTION, OFF ABIOLA WAY, ABEOKUTA

WBS 1269
TUESDAY 28TH NOVEMBER, 2023

AKORI EKO: AHON, AGBARA IYE ATI IKU (APA KINNI)


KOKO EKO: OHUN EELO IKU
IBI KIKA: OWE 18: 21
Ahon je eya kekere kan ninu ara eniyan, o si wulo ni pataki fun oro siso. Bi ijanu
se wa fun awon ohun irinna bii keke. keke ologeere (Okada), moto ayokele, moto
nla gbogbo, oko oju irin, oju omi ati ti ofurufu, fun idari lati ibi kan si ekeji, bee
gege ni ahon je ninu ara ehiyan lati dari aye eniyan kookan si iye tabi iku., si
iparun tabi ayo, npa ti emi ati nipa ti ara pelu. Jakobu 3:4-10.

A o wo die lara ona ti ahon le gba tuko aye kristeni si ipa iku ayeraye ti orun
apaadi, niwon igba ti kristeni ba loo ni awon ona wonyii:

1. IRO PIPA:- Iro pipa je ohun ti o buru jayi ninu igbe aye kristeni, o si je iwa ti
inu Olorun ko dun si. I Kor. 6:9A, Matt. 5:37, Kol 3:9.
Eko yi nro enikookan wa lati je olotito ninu ona wa gbogbo.

2. ISORO WERE:- Ki ise ohun ti o dara ki kristeni kan maa soro saa lai ko le ko
ara re ni ijanu. Awon oro ati orisirisi asa ti awon eniyan aye nos loni ni opo
kristeni ko ri bi ohun ti ko dara, awon oro were eyiti awon alaigbagbo maa nso
ati awon asa aye ti ko ba ife Olorun mu gbodo je ohun irira fun ojulowo kristeni.
Matt. 12: 36-37; Orin Dafidi 39: 1-2. Oro enu wa gbodo dara nitoripe idajo
Olorun nduro de enikookaħ lati jihin bi a ti se lo ahon wa, Efesu 4: 29

3. EEBU ATI EPE SISE:- Ohun ti Bibeli pe awa kristeni ni eda titun. II Kor. 5:17.
Sugbon o je ohun iyalenu wipe awon kristeni kan si wa ti won nfi ahon won bu
eebu ati epe sise, awon iwa wonyi ko le fi wa han gegebi eda titun rara.
Nitorinaa, a gbodo jawo ninu awon iwa buburu yi ni kiakia. Romu 12: 14;
Jakobu 3: 10-11.

4. ORO EYIN ATI ORO IGBERAGA GBOGBO:- Oro eyin ati oro igberaga tun je
ona kan pataki ti satani nlo lati ti kristeni lo sinu egbe ayeraye, ko ye ki kristeni je
asoro eni leyin tabi agberaga. Awa ni a wa nibe ati oro eyin je aisan buburu ninu
aye kristeni, eyiti o ye ki a gbadura daradara lati bo ninu re. Orin Dafidi 15: 1-3.
Ti o ba je lotito ni a nfe iye ati ojurere Olorun, a gbodo yera kuro ninu iwa ibi yi.
1 Peteru 3: 10.

Lakotan, o di dandan fun gbogbo kristeni ti o fe de ijoba Olorun nikeyin lati sora
nipa lilo ahon ni ilokulo, ki a si yera kuro ninu awon iwa buburu ti ati menuba ninu
eko yi.
MAT. 10:8 (INTERNATIONAL SECRETARIAT)
4, EBENEZER CHURCH ROAD, OLUWO JUNCTION, OFF ABIOLA WAY, ABEOKUTA

WBS 1269
TUESDAY 5TH DECEMBER, 2023

AKORI EKO: AHON, AGBARA IYE ATI IKU (APA KEJI)


KOKO EKO: OHUN EELO IYE
IBI KIKA: MATTIU 12: 37
Loni, a o maa tesiwaju ninu eko ti a bere ni ose ti o koja ti o da lori AHON,
AGBARATYE ATI IKU. Ohun ti a o maa se agbeyewo re loni ni bi o se le je iye
fun awa kristeni ati ona ti a le gba loo.

Ahon je atuko aye kristeni sinu iye nipa ti ara ati iye ayeraye ninu Paradise,
niwon igba tikristeni ba loo ni awon ona wonyii:

1. SISO ORO OORE-OFE: Nigbati a ba n so nipa oro oore-ofe, a nso nipa oro
daradara, oroitunu, oro ti o nfi ni lokan bale, oro ti o nfi eniyan han gegebi eda
titun ati ero si ijoba Olorun. Kol. 4: 6; Efesu 4: 29. Kristeni tooto gbodo maa ranti
wipe a o jihin fun Olorun lojo kan ni pataki ona ti a gba lo ahon wa, nitori idi evi, a
gbodo maa fi ahon wa tun ohun ti o baje se, ki a si maa so oro oore-ofe iru eyi ti
yoo maa mu inu awon ti o ba ngbo dun. Efesu 4: 29. Pelu gbogbo inunibini ti
awon cmo baba Josefu se si, sibe oro itunu ni o so fun won. Gen. 50: 19-21

2. FIFI AHON WA GBADURA: Gegebi omo Olorun tooto, ohun ti o ye wa ni lati


maa fi ahon wa gbadura nigba gbogbo, nitoripe omo alase ati omo Oba orun ni a
je, ohunkohun ti a ba si fi ahon wa beere ni Olorun yoo se fun wa. I Tim. 2: 1,
Johannu 16: 23, Jakobu 5: 16. Siso ohun rere nipa aye wa, ojo ola wa ati orile
ede wa je adura, yoo si wa si imuse.

3. KIKO ORIN IYIN ATIORIN EMI SI OLORUN: Iyin Olorun ni enu wa ni gbogbo
igba a maa mu inu Olorun dun si wa, nitoripe eyi nse afihan wipe a mo riri oore
Re ninu aye wa, bakannaa ni Bibeli so fun wa wipe ninu ohun gbogbo, a gbodo
maa dupe. Orin Dafidi 135: 3; Kol. 3: 16. Nigbati a ba nko orin iyin ati orin emi
si Olbrun, eleyi a maa mu ki awon emi esu wariri, nitoripe orin iyin ati orin emi nfi
okan wa bale wipe aju asegun lo nipa eje ti o ngbani la, Paulu ati Sila ko lo
ohunkohun bikose orin iyin ati orin emi si Olorun nigbati won wa ninu tubu,
Olorun si ran angeli Re lati lo tu won sile. Ise Ap. 16: 25-26

4. WIWAASU IHINRERE: Ise nla pataki ti Jesu Oluwa gbe le wa lowo ni ise
iwaasu ihinrere, osi je ohun ti o je Olorun logun, eyiti o mu ki o yonda JesuKristi
omo Re kansoso fun araye. Matt.10:7. Lilo ahon wa fun iwaasu ijere okan dara
pupo, bi a si ti nse eyi ni omo ijoba orun apaadi yoo maa dinku ti omo ijoba
Olorun yoo si maa po si. Marku 16: 15; II Tim. 4: 2.

Ti a ba le maa lo ahon wa ni awon ona ti a la sile fun wa ninu eko toni, o daju
wipe a o jogun aye yi, a o si ni iye ainipekun.
MAT. 10:8 (INTERNATIONAL SECRETARIAT)
4, EBENEZER CHURCH ROAD, OLUWO JUNCTION, OFF ABIOLA WAY, ABEOKUTA

WBS 1270
TUESDAY 12TH DECEMBER, 2023

AKORI EKO: AHON, AGBARA IYE ATI IKU (APA KETA)


KOKO EKO: APEERE AWON TI O FI AHON WON FA EGUN, IPARUN ATI IKU
IBI KIKA: JAKOBU 3: 8
Ni itesiwaju eko ti a ti nba bo lori AHON, AGBARA IYE ATI IKU, loni, a o se
agbeyewo awon ti o fi ahon won fa egun, iparun ati iku sinu aye won. Ti a ba nfi
okan ba eko yibo lati eyin, a ori wipe ona ti o ba wu eniyan ni o le lo ahon re si,
onakona ti eniyan ba si lo ahon re si ni yoo mu lo si orun rere tabi orun apaadi
nikeyın.

Awon eniyan kan ti fa iku ati iparun ayeraye sinu aye won nipa aikiyesi oro enu
won. Bayi, a o wo die ninu won:

1. OBA FARAO: Oba Farao ni eniti Olorun ran Mose ati Aaroni si lati yonda
awon omo Israeli lati lo sugbon esi ti oba yi fi dahun ni wipe “ Tani Oluwa ti emi
yoo fi gba ohun re gbo?" Eksodu 5: 1-2, sugbon nikeyin, o segbe sinu okun
pupa ati gbogbo awon omo ogun re. Eksodu 14: 22-25.

2. IJOYE KAN NI SAMARIA: Ijoye yi je eniti o sunmo oba pekipeki, Olorun ran
wooli Elisha lati fi okan awon ara ilu Samaria bale nipa pe iyan ti o ti mu fun ojo
pipe yoo di ohun igbagbe laarin ojo kan sugbon ijoye ara Samaria wipe ko le
seese, o koju iranse Olorun lati so fuu un pe eyi ko le ri bee, nipa eyi iranse
Olorun so fun un pe ileri Olorun yoo wa si imuse sugbon ijoye yi ko ni je ninu re,
eyi si ri be nitori o fi ahon re ba Oluwa jiyan. II Awon Oba 7: 1-2, 19-20.

3. AWON OMO WEWE TI O SORO LODI SI ELISA- nigbati Elisa mbo lati ibi ti a
ti gba oga re kuro ni odo re, awon omo keekeke mejilelogoji ri, won si fi se yeye
wipe, ‘apari goke lo”. Elisa fi won re nitori oro enu won yi, eranko beari meji si pa
won run. 2 Oba 2:23-24

4. ANANIA ATI SAFIRA: Anania ati Safira fi ahon won pa iro niwaju awon
Aposteli, won kuna lati so otito nigbati won se ohun ti o lodi si isokan ti awon
Aposteli ni nipa tita awon ohun ini won fun igbeleke ise Oluwa. Won fi ahon won
paro, won sis eke si Emi mimo, awon mejeeji si segbe Ise Ap. 5: 1-10

Awon die ti a fi se apeere fun wa loni gbodo je eko fun wa lati sora nipa lilo ahon
wa, ki o ma baa ti wa lo sinu iparun.
MAT. 10:8 (INTERNATIONAL SECRETARIAT)
4, EBENEZER CHURCH ROAD, OLUWO JUNCTION, OFF ABIOLA WAY, ABEOKUTA

WBS 1271
TUESDAY 19TH DECEMBER, 2023

AKORI EKO: AHON, AGBARA IYE ATI IKU (APA KERIN)


KOKO EKO: APEERE AWON TI WON FI AHON WON GBA IYE SINU AYE WON
IBI KIKA: KOLOSSE 4:6
Loni, a o mu eko lori AHON, AGBARAIYE ATI IKU wa si idanu duro nipa sise
agbeyewo awon ti won fi ahon won gba iye sinu aye won, nitoripe won lo ahon
won ni ona ti o se itewogba niwaju Olorun.

A o wo apeere die lara awon ti won pa ahon won mo nipa kikiyesi ase Olorun,
won si ti ipa bee fa iye ti ara ati ti emi sinu aye won. Die ninu won niwonyi:

1. BALOGUN ORUN: Bi okunrin yi ti je alagbara. akikanju ati olori ogun ninu aye
yi to, sibe ko je ki ipo ti o wa nipa ti ara bo oun loju lati ma bowo fun olori ogun to
ju olori ogun aye yi lo ti ise Jesu Kristi, eniti nigbati omo re nse aisan, to wa lati
be Jesu fun iwosan omo odo re, Olugbala setan lati baa lo sile sugbon ommo
wipe alagbara ti o ju oun lo ni oun wa ba, o so fun Jesu wipe ki o so kiki oro kan,
ara omo odo oun yoo si da. Matt. 8: 8. Oro ti o fi ahon re so yi mu ki omo re gba
imularada ni kiakia.

2. OLE ORI AGBELEBU: Okunrin yi ko se ise kankan ti o ye ki o le mu de ijoba


orun sugbon ahon re gbaa sile loju iku, nigbati ɔ so fun Jesu wipe ki o ranti oun
ni ijoba orun. Olugbala si fi onte te ibeere re loju kannaa. Luku 23: 40-43.

3. ABIGAILI: Obinrin yi je ologbon eniyan sugbon oko re je alaibikita ati eniti oye
ku fun. Nipa ona irele ti obinrin yi gba lo ahon re, iparun ti o ye ki o de ba gbogbo
idile re ni a mu kuro I Sam. 25: 23-25, 32-34

4. OLORI OGUN AADOTA (KETA): Owe kan wipe "Eniti o jin si koto, o ko ara
iyooku logbon", eyi ri be nipa ogbon ati emi irele ti olori ogun aadota ti oba
Ahasiah ran lati lo mu wooli Elijah lo, olori ogun adota meji ni oba ti koko ran
sugbon ti wooli Elijah pe ina sokale sori won, ti o si jo won run, sugbon olori ogun
aadota keta yi mo pe iranse Olorun tooto ni wooli Elijah ise, o si lo bee wipe ki o
da emi oun si. Nitori ohun ti o se yi, Olorun ran angeli si wooli Elijah pe ki o baa
lo si odo oba yi. Aseyori meji ni olori ogun aadota keta yi se, ekinni ni pe emi
enikeni ko segbe beeni osi tun mu eniyan Olorun de odo oba gegebi ise ti a ran
an. II Awon Oba l: 13-14.

5. RUTU: Itan Rutu je ipenija nla fun gbogbo kristeni ti o fe lati de ijoba orun
nitoripe laini ireti ni Rutu gba lati tele iya oko re Naomi pada si ilu re laise wipe o
ni ibatan tabi iyekan nibiti o nlo sugbon pelu oro enu Rutu, iya oko re gba laaye
lati tele oun, eleyi t io yori si ayo ati ogo nla fun Rutu. Rutu 1: 16-17. Ona ti Rutu
gba lo ahon re so o di iya nla Josefu ti ise baba Jesu Kristi Oluwa. Matt. 1:5

Lakotan, eko lori ahon wa ni lilo ni ona tio dara je oranyan fun gbogbo omoleyin
Kristi ki isin wa le jeitewogba niwaju Olorun. Jakobu 1: 26.
MAT. 10:8 (INTERNATIONAL SECRETARIAT)
4, EBENEZER CHURCH ROAD, OLUWO JUNCTION, OFF ABIOLA WAY, ABEOKUTA

TUESDAY 26TH DECEMBER, 2023

IBEERE ATI IDAHUN

You might also like